THE SEED
“I have been crucified with Christ. It is no longer I who live, but Christ who lives in me. And the life I now live in the flesh I live by faith in the Son of God, who loved me and gave himself for me.” Galatians 2:20 ESV
The process of becoming born again is an experience that should be close to the heart of a new believer. This is especially true if you were not born as a Christian and neither went to church growing up. One thing is certain, once you accept Jesus and confess and forsake your sins, changes should come from within you and manifest physically. Your new birth radiates from inside to outside. This is the point whereby, you make certain decisions about your lifestyles, friendships. You will have to allow Jesus to have the final say, if you only profess Jesus as your Saviour i.e. He is the person who saved you, yet if you do not make him your Lord; you are short-changing yourself. Being the Lord of your life means Jesus will be in total control your life. You will hear from Him concerning those decisions that are important to your life. Where He asks you to go, you will go there. The key verse today reminds you that you no longer live for your own selfish gains, but rather live a life that portrays Christ, who lives in you. Accepting His salvation means accepting His Lordship to rule over you. The deliverance, the blessing and support that are attached to your salvation are numerous, the key to these are accepting Jesus as the Lord and Saviour. Once you surrender all, then you let Him take the lead. The ultimate is total obedience to His words.
BIBLE READING: Philippians 2:5–11
PRAYER: Heavenly Father, please help me to trust your providence and faithfulness to work mightily
JÉSÙ,OLÚWA ÀTI OLUGBALA WA.
IRUGBIN NAA
“A tí kàn mí mọ agbelebu pẹlu Kristi: ṣugbọn mo wà láàyè, sibẹ kí iṣe èmi mọ, ṣugbọn Kristi wà láàyè nínú mi: wiwà tí mo sì wà láàyè nínú ara, mo wà láàyè nínú ìgbàgbọ ọmọ Ọlọrun, ẹnití o fẹ mi, ti o sí fi òun tikararẹ fún mi.” Galatia 2:20
Ilana láti di atunbi jẹ iriri ti o yẹ ki o sunmọ ọkan onigbagbọ tí o di titun ninu Kristi. Eyi jẹ otitọ, paapaa ti a ko ba bi ọ bi onigbagbọ ati pe o ko lọ si ile ijọsin nígbà ti o n dàgbà. Ohun kan daju, ni kete ti o ba gba Jesu ti o jẹwọ Rẹ̀, ati pé o kọ awọn ẹṣẹ rẹ silẹ; awọn iyipada yẹ ki o wá lati inu rẹ, ti yio sí farahan nipa ti ara. Atunbi tuntun rẹ gbọdọ tan lati inu si ita. Eyi jẹ lọ̀gan ti o ba ṣe awọn ipinnu kan nipa awọn igbesi aye rẹ, ibadọrẹ, ati bẹbẹ lọ, iwọ yíó sí gba Jesu láàyè lati ní àṣẹ lórí ọrọ rẹ. Sibẹsibẹ, ti o ba jẹwọ Jesu nikan gẹgẹbi Olugbala rẹ ati bẹbẹ lọ. Ó jẹ ẹni ti yio gba ọ là, sibẹ o kọ̀ láti ṣe e ni Oluwa rẹ, iwọ nke timọtimọ pẹlú Kristi kúrú. Jíjẹ Oluwa fún igbesi aye rẹ tumọ si pe Jesu yíó wa ni iṣakoso lapapọ fún igbesi aye rẹ. Iwọ yíó gbọ lati ọdọ Rẹ nipa awọn ipinnu wọnni ti o ṣe pataki si igbesi aye rẹ. Nibiti O sọ pe ki o lọ, iwọ yíó lọ sibẹ. Ẹsẹ ọrọ Bíbélì t’oni nran wa leti pe iwọ ko gbe aye fun ere imọtara-ẹni-nikan ṣugbọn kuku gbe igbesi aye ti o ṣe afihan Kristi, ẹniti ngbe inu rẹ. Gbigba igbala Rẹ̀ tumọ si gbigba Oluwa Rẹ, O ní lati ṣe akoso lori rẹ. Idande, ibukun ati atilẹyin ti o so mọ igbala rẹ pọ púpọ, kọkọrọ si iwọnyi ni gbigba Jesu gẹgẹbi Oluwa ati Olugbala. Ni kete ti o ba fi gbogbo rẹ silẹ, lẹhinna gbà a láàyè ki O ṣáájú. Ipari ni, ìgbọràn lápapọ̀ si awọn ọrọ Rẹ.
BIBELI KIKA: Fílípì 2:5-11.
ADURA: Baba wa Ọrun, jọwọ ran mi lọwọ lati gbẹkẹle ipese ati otitọ Rẹ lati le ṣiṣẹ pẹlu agbara nipasẹ mí. Amin.