THE SEED
“My shield is God Most High, who saves the upright in heart.” Psalms 7:10 NIV
What does a shield do? It’s a protective instrument that is designed to protect the user from harmful weapons from the enemy. For a shield to do its work, it must be worn when needed otherwise it is of no use to the owner. Bringing this knowledge to our Christian life, God through Christ is our shield, our protector from all spiritual and physical harm. It is our responsibility as children of God to put on Christ as our shield at all times so as to be protected from the flaming arrows of the enemy that might be shot at us anytime. According to Apostle Paul, we wrestle not against flesh and blood but against spiritual wickedness in high places. They have their evil plans spiritually to attack us before executing them physically. This is why we should depend totally on God who has dominion over both domains and trust the Holy Spirit’s instinct at all times to direct us away from the enemy’s attack. We should grow to know and understand the Holy Spirit’s instructions in directing us away from impending danger or the enemy’s traps on our path. The way to put on the spiritual shield is by walking in uprightness of heart and in obedience before God at all times, as well as reading God’s word consistently and praying without ceasing, by doing these we would be making provision to receive constant protection from God.
BIBLE READINGS: Ephesians 6:10-13
PRAYER: Lord Jesus, please help me to make you my shield by putting you on always to receive the appropriate defence when needed. Amen
ỌLỌ́RUN ÀSA NIPA TI ARÁ ATI NIPA TI ẸMI
IRUGBIN NAA
“Ọlọ́run ti o ga ni ààbò mi, ẹnì tí ó gba ọlọ́kàn diduro ṣinṣin la”. Psalm 7:10
Kini àsa nṣe? O jẹ́ ohùn èlò ti a ṣe fún idààbò bo fún àwọn tí wọn nlo fún ààbò kuro lọ́wọ́ ohun èlò búburú lati ọwọ ọ̀tá. Fún àsà làti ṣe iṣẹ́ rẹ, a ni láti gbé e wọ nígbàtí a bá nilo rẹ, lai jẹ́ bẹ ko le wúlò fún ẹni tí ó ni i. Ti a ba mu ìmọ̀ yi wá sinu ìgbé ayé Kristẹni wa, Ọlọ́run nipa Kristi ni ààbò wa, Oun ni àsà wà kúrò ninu idaloro nipa ti ara ati ti ẹmi. O jẹ ojúṣe wa bi ọmọ Ọlọ́run lati gbé Kristi wọ gẹ́gẹ́ bí ààbò wa nigba gbogbo lati le daabo bó wa kuro lọ́wọ́ ọfà iná ẹmi ti ọ̀tá ti a le ta síwá nígbàkúùgbà. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, kii ṣe ẹ̀jẹ̀ ati ẹran ara ni a nba já ìjàkadì ṣùgbọ́n àwọn ẹmi búburú ibí gíga. Wọn ni ero búburú wọn láti fi dojú kọ wa, ki wọn to gbé e jáde nipa ti ara. Eredi ni yí ti a fi níláti gbẹkele Ọlọ́run ti O ńṣe àkóso lori ibi gbogbo, ki a si gbẹkele ìtọ́ni ẹmi mímọ; nígbàkúùgbà lati máà tọ ni, kuro lọ́wọ́ ìdojúkọ àwọn ọ̀tá. A gbọ́dọ̀ dàgbà ki a si ni imọ ìtọ́ni tí ẹ̀mí mímọ nipa dídári wa kúrò lọdọ ewu tó nbọ tàbí ìdẹkùn ọ̀tá ní ojú ọ̀nà wa. Ọ̀nà lati lo àsa ẹmi ni, làti máà rìn ninu ọkàn pípé ati ìgbọràn níwájú Ọlọ́run nígbà gbogbo; ati láti máà ka ọrọ Ọlọ́run léraléra ki a si máà gbà àdúrà láì simi àti lai ṣe aarẹ, nípa ṣiṣẹ́ èyí a o máa pèsè silẹ fún idààbò bò lati ọdọ Ọlọ́run àṣíborí ati olùgbé já wa.
BIBELI KIKA: ÉFÉSÙ 6:10-13
ADURA: Jésù Olúwa rán mí lọwọ lati fi O ṣé àṣíborí tí ngo máa gbé wọ nígbà gbogbo ní igbenija tí ó yẹ nígbà tí mó nílò rẹ. Àmín.