THE SEED
“Then He asked them, “Why are you afraid? Do you still have no faith?”Mark 4:40
When a great storm arose and the waves beat into the ship, the disciples were so fearful while Jesus was sleeping peacefully. They were so fearful that they woke Him. Where is your first port of call when you are confronted with problems and tough situations? Your exclamation when anything sudden happens to you shows where your trust is. When the storms, winds and floods of life come, such as unpleasant circumstances that could result in some loss or discomfort physically, spiritually, emotionally, financially, materially and politically. The greatest storm of life is untimely death but the good news is that, you should not panic or become fearful, the storm stiller has power over death as well. Always know that the Lord is mindful of you and is always with you. In John 11:25-26 Jesus said unto her, I am the Resurrection and the life: he that believeth in me, though he were dead, yet shall live: And whosoever liveth and believeth in me shall never die. Believeth thou this? He is still saying to that troubling situation ” Peace be still” even as He said to the sea in those days. As the wind ceased at His voice, so will that situation cease as you call upon Him. Cry unto Him always for He is the One that can change all situations for us. Pray and present to Him those problems that make you fear.
BIBLE READINGS: Mark 4: 35 -44
PRAYER: O Lord grant unto me the power to continue casting my trust upon You in Jesus’ name Amen.
MÁ BẸ̀RÙ KÉ PEE YÍÒ TỌ́JÚ RẸ
IRUGBIN NAA
Èé ṣe ti ẹyin fí ńṣe ojo bẹ́ẹ̀? ẹ kó tí i ní igbagbọ síbẹ̀? MARKU 4:40
Nígbàtí Ìjì Ńlá rú sókè ti Ìgbì náà n bí sínú ọkọ̀, to bẹ tí ọkọ̀ náà fi kún fún omi, ẹ̀rù bà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gan-an, Jésù si ń sùn ní àlàáfíà. Èrùbà wọ́n débi pé wọ́n jí i; níbo ni ibí ìpè rẹ àkọ́kọ́, nígbà tí o bá koju awọn iṣoro ati awọn iporuru? Gbólóhùn ìbẹ̀rù rẹ, nigbati ohunkohun ba ṣẹlẹ si ọ lójijì fihan ibi ti igbẹkẹle rẹ wà. Nígbàtí awọn iji lile, àtẹ̀gùn lílé ati awọn iṣan omi ti aye; bi awọn àjálù ti o le ja si ipadanu tabi aibalẹ ọkàn nipa ti ẹmi, nipa ti iṣuna, ọrọ, ati ti iṣelu ti o tobi julọ. Iji aye le jẹki iku aitọ̀jọ̀ tọ sí ènìyàn, ṣugbọn iroyin ti o dara ni pe, ko yẹ ki o fòyà tabi bẹru, enití o le da iji naa duro, ní agbara lori iku bakannaa. Mọ, nigbagbogbo pe Oluwa nṣe iranti rẹ ati pe o wa nigbagbogbo pẹlu rẹ. Nínu Johannu 11: 25-26 Jesu wi fun u pe Emi ni ajinde ati iye, ẹniti o ba gbà mi gbọ, bi o tilẹ ti kú, yio yè ati awọn ti o ba ti wa laaye ti o ni ìgbàgbọ́ ninu mi ki yoo kú lailai. Njẹ o gbà èyí gbọ́? O si nsọ fun rírú omi pe “Dakẹ Jẹjẹ ” bi o ti ba awọn omi wi ní ọjọ́ wọnnì. Bi afẹfẹ ti da ọwọ dúró ni gbigbọ ohun Rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wàhálà rẹ yíò dópin bi o tí ṣe nke pe e. Ke pe e nigbagbogbo nítorí O jẹ ẹniti o le yi gbogbo awọn ìdojúkọ rẹ pada. Gbadura ati ki o si gbé àwọn ìṣòro ti o nba ọ lẹ́ru fun un.
BIBELI KIKA: Máàkù ori 4:35- 44
ADURA: Oluwa Fun mi ni agbara lati tẹsiwaju nipa gbigbẹkẹ mi le ọ ni orukọ Jesu Amin