THE SEED
Keep your heart with all diligence for out of it springs the issues of life. Proverbs 4:23
Apart from the tongue, another very dangerous organ of man is the heart because all the thoughts and issues of life, (whether pure or impure) emanate from there. Hence, according to Proverbs 4:23, you must keep your heart with all diligence for out of it springs the issues of life. Your expression of love towards another is as you conditioned your heart to do. This will propel you to love, give, share with, befriend or forgive him or her. On the other hand, you hate, begrudge, envy, deny, abuse, or curse him/her where you generate negativity towards him/her. But if this heart has been liberated by the cleansing work of the Lord, made pure, liberated and prepared for heaven, then good things of life will come and stay in such a life. I beseech you therefore my beloved, let us carry our rotten, weed laden, evil, wicked hearts to God and cry unto Him to have mercy on us, to weed and liberate our hearts from all evil and wickedness. As the work of liberation progresses in our hearts, physical progress and well-being will manifest. Is your heart pure? Are you prepared to meet Him? Once our hearts are pleasing to God, He goes out to fight for us even without our asking Him! When Jesus shall come to take His own away, He will only take those whose hearts are pure and prepared for the Kingdom of God. Surrender unto Him and let Him have His way concerning you. Repent today.
BIBLE READINGS: Psalm 51:10-14
PRAYER: Lord, help me to keep my heart with all diligence in Jesus name. Amen.
JẸ MÍMỌ́ KÍ O SÌ MÚRA SÍLẸ̀
IRUGBIN NAA
“Ju gbogbo ohun ti o n pamo lo, pa aya re mo, nitori pe lati inu re wa ni orisun iye”
Iwe Owe 4:23
Yàtọ̀ sí ahọ́n, ẹ̀yà ara ènìyàn mìíràn tí ó léwu ju lo ni ọkàn nítorí gbogbo èrò àti ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé , (yálà mímọ́ tàbí àìmọ́) máa ń jáde láti ibẹ̀. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Iwe Òwe 4:23, o gbọ́dọ̀ pa ọkàn rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo àya re nitori láti inú rẹ̀ máa ń mú ọ̀rọ̀ ìyè jáde. Ìfihàn ìfẹ́ rẹ sí omo elomíràn da lo ri bi ọkàn re ti rii sii. Èyí yóò mú ọ lọ nínu ifẹ,fi fún ni, pín ohun kan pẹ̀lú re, ṣe ọ̀rẹ́ tàbí dáríjì í . Ní idakejì, o le kórìíra,se ìlara, sẹ́,se ìlòkulò oro sii, tàbí bú u níbi tí o ti hu ìwà burúkú sí i. Ṣùgbọ́n tí ọkàn yìí bá ti di òmìnira nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ Olúwa, tí ó jẹ́ mímọ́, òmìnira àti ìmúrasílẹ̀ fún ọ̀run, nígbà náà àwọn ohun rere ìyè yóò wá dúró si ínú irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀. Mo bẹ̀ ọ́ nítorí náà olùfẹ́ mi, ẹ jẹ́ kí á gbé ọkàn wa tí ó ti bàjẹ́, ati ọkàn búburú yi sí Ọlọ́run kí a sì ké pè é láti ṣàánú fún wa, láti dá ọkàn wa sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ibi àti ìwà búburú. Bí iṣẹ́ ìdásílẹ̀ ṣe ń tẹ̀síwájú nínú ọkàn wa, ìlọsíwájú ara àti ìlera yóò hàn. Ṣé ọkàn rẹ mọ́? Ṣé o ti múra sílẹ̀ láti pàdé Rẹ̀? Ní kété tí ọkàn wa bá ti dùn mọ́ Ọlọ́run, yi o jáde lọ jà fún wa kódà láìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀! Nígbà tí Jésù bá wá láti mú awon eniyan rẹ̀ kúrò, òun nìkan ni yóò mú àwọn tí ọkàn wọn mọ́ tí wọ́n sì múra sílẹ̀ fún Ìjọba Ọlọ́run. Fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún un kí ó sì gba ni aye ní ọ̀nà rẹ̀. Ronupiwada loni.
BIBELI KIKA: Psalmu 51:10-14
ADURA: Oluwa, ran mi lọwọ lati pa ọkàn mi pẹlu gbogbo aya mo ni Orukọ Jesu. Amin.