THE SEED
“When a strong man, fully armed, guards his own house, his possessions are safe. But when someone stronger attacks and overpowers him, he takes away the armour that the man trusted … Luke 11: 21-22 NIV
John 10:10 warns us about Satan’s mission, which is to steal, kill and destroy. Important parts of your life are prone to attack, you or a family member; whereby Satan manifests in different ways. It is not the person who is carrying out these deeds, but he/she is under the influence of Satanic power- Ephesians 6:12 explains that we wrestle against principalities, against powers, against the rulers of the darkness of this age, against spiritual hosts of wickedness in the heavenly places.” There is a need for you or the person to be aware of the real enemy before you can plan your defence and way of escape. There are many reasons why Satan attacks and it’s not because we do not pray enough. Job was a fervent man before God. Yet he faced attack in numerous ways. The attack maybe when you are vulnerable, strong, starting a new project or moment of happiness. Commit the situation into the hands of God for total deliverance through prayer, keep in mind that your weapons of warfare are not carnal, but mighty through God to the pulling down of strong holds 2 Cor 10:4. Most importantly, when you become victorious, do not just become lazy and forget your prayers, keep your guard up and continue to defend your territory.
BIBLE READINGS: Luke 11: 14-27
PRAYER: Lord, deliver me and my family from the evil spirits that can kill.
DI DOJÚ KỌ̀ Ẹ̀MÍ TÍ Ó LÉ PANI
IRUGBIN NAA
Nígbàtí ọkùnrin alágbára ti o hamora bá nṣọ́ àfin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ a wa lí àlàáfíà. Ṣùgbọ́n nígbàtí ẹnití ó li agbára ju ú ba kọ lu ú, ti o si ṣẹ́gun rẹ̀, a gba gbogbo ìhámọ́ra rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀le li ọwọ rẹ… Luku 11:21-22
Ìhìn rere Johannu 10:10 kìlọ̀ fún wa nipa ìṣe ti Satani wa lati ṣe, lati jale, lati pa ati lati parun. Pàtàkì nínú ìgbésí aye rẹ̀, ní ó wà fún idaloro, ìwọ àti àwọn ẹbi rẹ nibiti Sátánì gbé máà ń fi ara hàn ni oríṣiríṣi ọ̀nà. Ki i ṣe ènìyàn fún rárá rẹ ní o ńṣe àwọn nkan wọ̀nyí bikoṣe pé o wa ni abẹ iṣakoso Sátánì; Éfésù 6:12 ṣe àlàyé pé kí ìṣe ẹ̀jẹ̀ ati ẹran ara ni a nba já ìjàkadì ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ibi okuku ayé yí ati awọn ẹmi búburú oju ọ̀run. O nílò láti mọ ni pato, irú ẹnití ọ̀tá jẹ́ kí o tó mọ ọ̀nà làti gbaradi fun ọ̀nà àbáyọ. Eredi ti Satani fi ń kọlù wa pọ púpọ̀, kii si iṣe pe nitori a ko gbadura to, Jobu jẹ eniyan ti o ni itara niwaju Ọlọ́run. Sibẹsibẹ o ní idojuko ni ọpọlọpọ. Awọn ìdojúkọ lé jẹ́ nigbati o ko bìkítà, ailagbara tabi o bẹrẹ iṣẹ akanṣe tuntun kán tabi nígbà akoko idunnu. Fi irú ipo yii si ọwọ Ọlọrun fun itusile lapapọ nipasẹ adura; ni lọ́kàn pe awọn ohun ìjà ogun rẹ kì í ṣe nípa ẹran ara ṣùgbọ́n o lágbára nípa ti Ọlọ́run láti wo àwọn ibi gíga lulẹ̀ 2 Kọ́ríńtì 10:4. Ní pàtàkì jù lọ nígbà tí ẹ bá ṣẹ́gun, ẹ má ṣe di ọ̀lẹ lásán kí ẹ sì gbàgbé àdúrà yín, ẹ máa ṣọ́ra kí ẹ sì máa gbáradi láti dá ààbò bo àgbègbè yín.
BIBELI KIKA: Luku 11: 14-27
ADURA: Oluwa tu èmi àti idile mi silẹ kuro lọwọ àwọn ẹmi buburu ti o le pa mi. Amin