DISCOURAGING FACES

THE SEED

“Be not afraid of their faces: for I am with thee to deliver thee, saith the Lord” Jeremiah 1: 8 (KJV)

God told Jeremiah in this passage to keep the focus on Him, to only concentrate on the God who predestined and chose him for prophethood. There will always be those who will look down on us and count our words as nothing. When we are doing the work God has given us, they will come to you with negative comments, aimed at discouraging you. God says we should not be afraid of them, they plan to throw us off balance and turn us into a people-pleaser rather than a pleaser of God, our Father in Heaven, we end up missing His perfect will for our lives, may we not fall into such. Being a pleaser of people comes with the consequences of losing God. If we allow people’s attitudes, utterances and body language to dissuade us from focusing our attention on doing God’s work, then we should get ready to face God’s rejection. This is established in verse 17 of Jeremiah Chapter 1, where God told the Prophet Jeremiah that “Do not be terrified by them or I will terrify you before them.” Beloved, we need not fear people because they can not save us, but we need to always pay our allegiance to God who called us, can deliver us and will always be our aid in times of difficulty, as long as you are doing what He called you to do.This is the confidence that allows us to always speak and act in truth.

BIBLE READING: Jeremiah 1: 1-8

PRAYER: Lord, please strengthen me that I may focus on you and not be swayed by the harsh opinions of those who wish to discourage me in the Ministry you have given me. Be my deliverer and helper always in Jesus’ Name. Amen.

 

OJU ÀWỌN ARẸ̀WẸ̀SÌ

IRUGBIN NAA

“Maṣe bẹru oju wọn: nitori mo wa pẹlu rẹ lati gba ọ, ni Oluwa wi.” Jeremiah 1:8

Ọlọ́run sọ fún Jeremáyà nínú ọ̀rọ̀ náà pé kí ó ni àfojúsùn sí ọ̀dọ̀ Òun, láti tẹ ojú mọ́ Ọlọ́run tí ó ti yan ṣáájú , tí o sì fún ní ipò wòlíì. Nigbagbogbo, ni àwọn èniyàn ti nfi oju tẹ́ńbẹ́lú wa ti wọn si nka ọrọ wa si asan. Nígbà tí a bá ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi fún wa, awọn ní yíò kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ burúkú láti pa wá lẹ́nu mọ, tí wọ́n sì máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Ọlọrun sọ pe a ko gbọdọ bẹru wọn, wọn gbero lati sọ wa sinu iporuru ati yi wa pada si olu tẹ eniyan lọ́run dípò olu tẹ Ọlọrun Baba wa ni ọrun nitorinaa a padanu ifẹ pipe rẹ fun igbesi aye wa. Jíjẹ́ ẹni tí ntẹ àwọn ènìyàn lọ́rùn ń wá pẹ̀lú àbájáde pípàdánù atìlẹ́yìn Ọlọrun. Bí a bá jẹ́ kí íhùwàsi, ọ̀rọ̀ sísọ àti fífi ara sọ̀rọ̀ mú wa yi ojú wa padà kúrò nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nígbà náà a ti múra tán láti dojú kọ ìkọ̀sílẹ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú. Èyí sì wà nínú ẹsẹ 17 ti Jeremáyà orí kìíní, níbi tí Ọlọ́run ti sọ fún wòlíì Jeremáyà pé “Má ṣe jẹ́ kí wọ́n da àyà fò ọ, ti o ba ṣe bẹ́ẹ̀, Èmi yóò mú ọ fòyà níwájú wọn.” Olufẹ a ko nilo lati bẹru eniyan nitori wọn ko le gba wa la, ṣugbọn a nilo lati fí ijolotitọ wa nigbagbogbo han si Ọlọrun ti o pe wa, ti o le gba wa, ati pe yoo jẹ iranlọwọ wa nigbagbogbo ni awọn akoko iṣoro, niwọn igba ti o ba n ṣe ohun ti O pe ọ si lati ṣe. Eyi ni ìfọ̀kànbalẹ̀ ti o jẹ́ ki a maa sọ̀rọ̀ ki a si maa ṣé ohun gbogbo nínú òtítọ́.

BIBELI KIKA: Jeremáyà 1 :1- 8

ADURA: Oluwa jọwọ fun mi ni okun ki emi ki o le maa wo Ọ; ki a ma si ṣé ṣi ọkàn mí kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú èrò búburú gbígbóná, láti ọwọ àwọn ẹni ti o ṣetan láti mú mi kúrò ninu ìṣẹ́ ìríjú tí ẹ fun mi. Ẹ jẹ́ olugbala ati oluranlọwọ mi nigbagbogbo ni orukọ Jesu. Amin

Leave a comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *