THE SEED
“But don’t rejoice because evil spirits obey you; rejoice because your names are registered in heaven” Luke 10:20 NLT.
The above verse was Jesus’ response to the 72 disciples when they returned from their missionary trip. They were amazed that even the evil spirits and demons obeyed them when they used the name of Jesus. It may surprise us why Jesus told them not to rejoice over this, rather they should rejoice that their names are written in the Book of Life. This is a warning to us that when we see Ministers or Pastors, who operate in the realm and capacity of casting out demons and doing all manner of miracles, this performance alone does not indicate that they are holy or that their salvation is sure and rooted in Jesus Christ alone. Jesus Christ told the disciples that He saw Satan fall from heaven like lightning, which meant that the devil was already defeated by the name of Jesus. Jesus told us in the book of Matthew 7:22-23 that many would be rejected on the last day because they are workers of iniquity, even though they professed to have done many miracles and cast out demons in Jesus’ name. Let our focus as children of God be mainly on our Salvation and not chase after miracles, because many out there are just performers and have no power and fear of God in them. Let us not be deceived.
BIBLE READING: LUKE 10: 1-20 NLT.
PRAYER: Dear Lord, I pray that you will help me and fill me with more of your holy spirit so that I will not be deceived in Jesus’ name. Amen.
MÁṢE YỌNDA ARA RẸ FÚN ÌTÀNJẸ
IRUGBIN NAA
“Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ sí èyí pé, àwọn ẹmi okunkun nforibalẹ̀ fún yin: ṣùgbọ́n kí ẹ kúkú yọ, pé, a kọ̀wé orúkọ yín lọ́rùn”. Luku 10 :20.
Ẹsẹ Bibeli tó wà lókè yìí jẹ́ ìdáhùn Jésù sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìléláàádọ́rin [72] nígbà tí wọ́n dé láti irin-ajo ihinrere wọ́n pẹ̀lú Ìṣẹ́gun. O jẹ́ ìyàlẹ́nu fun wọ́n láti ri pé ẹ̀mí èṣù forí bá lẹ fún wọ́n nigbati wọ́n ló orúkọ Jésù. Ó lè yà wá lẹ́nu ìdí tí Jésù fi sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe yọ̀ lórí èyí, kàkà bẹ́ẹ̀, kí inú wọn dùn pé a kọ orúkọ wọn sínú ìwé ìyè. Ìkìlọ̀ nìyí fún wa pé nígbà ti a bá rí àwọn Òjíṣẹ́ tàbí Àwọn Olùṣọ́ Aguntan tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ìpele Ìjọba ẹ̀mí okuku lati lé awọn ẹmi èṣu jade ati ṣiṣe awọn iṣẹ iyanu. Iṣẹ-ṣiṣe yii nikan ko fihan pe wọn jẹ mimọ tabi pe igbala wọn daju tabi wọ́n fidimulẹ ninu Jesu Kristi nikan. Jesu Kristi sọ fun awọn ọmọ-ẹhin pe Oun ri Satani jabọ́ láti ọ̀run bí mànàmáná, èyí tó túmọ̀ sí pé orúkọ Jésù ti ṣẹ́gun èṣù tẹ́lẹ̀. Jésù sọ fún wa nínú ìwé Matteu 7: 22-23 pe ọ̀pọ̀ ni a o kọ silẹ ni ọjọ́ ikẹhin nítorí wọ́n jẹ́ Òníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ́wọ́ pé wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu, tí wọ́n sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ Jésù. Jẹ ki àfojúsùn wa gẹgẹbi awọn ọmọ Ọlọrun jẹ akọkọ lori igbala wa, ki a ma ṣe máa wa awọn iṣẹ iyanu kiri: nitori ọpọlọpọ awọn ti o wa lóde oni da bí eléré ìdárayá awọn oṣere ti ko ni agbara tabi ibẹru Ọlọrun ninu wọn. Ẹ ma jẹ́ ki a tan wa je.
BIBELI KIKA: Luku 10 : 1-20.
ADURA: Oluwa mi, mo gbaladura pe ki o ran mi lowo, ki o si fi Emi Mimo re tọ́ mi sii ki a ma baa tan mi jẹ́ loruko Jesu. Amin.