THE SEED
“I will make you exceedingly fruitful, and I will make nations of you, and kings shall come from you.” Genesis 17:6 NKJV
Divine fruitfulness can only come from God Almighty and when this happens, all eyes will see it and marvel. God is an abundant God and ever ready to give to his children in abundance. Before we can be divinely fruitful, we need to be divinely cleansed and divinely ready to remain in the realm of the spirit of God. Man is limited, but our God is not limited because He is the God of all flesh, there is nothing too difficult for him to do. When we do His will and He abides in us, we will experience a great turn-around because you cannot be serving the God of fruitfulness and not be fruitful. Ezekiel 34: 27 says, Also the tree of the field will yield its fruit and the earth will yield its increase, and they will be secure on their land. Then they will know that I am the Lord when I have broken the bars of their yoke and have delivered them from the hand of those who enslaved them. God is forever faithful to his words, all we need as man is to be faithful in our services to him and we will never be barren in any area of our lives. Abraham was faithful to God and he was divinely fruitful. Everybody wants the blessings of Abraham but do not forget that he paid his dues, pay your dues today; in your worship, dedication and holiness to God and then you will be assured of divine fruitfulness that the eyes have not yet seen, ears have not heard and human heart is yet to imagine.
BIBLE READING: Leviticus 26: 3-9
PRAYER: Oh Lord, give me the power and the grace to walk in your statutes and to keep your commandments in order to be fruitful in life. Amen
SI SO ÈSO LÁTI OKE WA
IRUGBIN NAA
“Èmi o sí mú ọ bí sí i púpọ̀ púpọ̀, ọ̀pọ̀ orile-ede li èmi o sí mú tí ọ̀dọ̀ rẹ wá, ati àwọn ọba ni yió tí inú rẹ jáde wá”. Genesisi 17:6.
Èso àtọ̀runwá lè wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Olódùmarè nìkan, nígbà tí o bá sì ṣẹlẹ̀, gbogbo ojú ni yio rí i, yio si ya ní lẹ́nu. Ọlọ́run jẹ́ Ọlọ́run ọpọlọpọ, Ó sì múra tán láti fi fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ṣaaju ki a to le so eso bi i ti atọrunwa, a nilo lati wa ni mimọ lọna bi i ti atoke wa ati ni imurasilẹ lati duro ni ìpele ti Ẹmi Ọlọrun. Ènìyàn ní ààlà ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa kò ní ààlà nítorí pé òun ni Ọlọ́run gbogbo ẹran-ara, kò sí ohùn tì o ṣòro fún un láti ṣe. Nígbà tí a bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀ tí ó sì ńba wa gbé , a ó ní ìyípadà ńláǹlà ní yíyíká nítorí ìwọ kò lè sin Ọlọ́run ti O nbukun fún ni kí a má sì so èso. Ìsíkíẹ́lì 34:27 sọ pé, Pẹ̀lúpẹ̀lù, igi pápá yíò so èso rẹ̀, ilẹ̀ yíò sì so èso rẹ̀, yíò sì wà láìléwu lórí ilẹ̀ wọn. Nígbà náà ni wọn yíò mọ̀ pé èmi ni Olúwa nígbà tí mo bá ti ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú àjàgà wọn, tí mo sì ti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n mu wọ́n lẹ́rú. Olóòótọ́ ni Ọlọ́run títì lai si ọ̀rọ̀ Rẹ̀, ohun ti a nilo gẹgẹ bi ènìyàn ni làti jẹ́ olotítọ nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí i, a ko si ni yàgàn ohunkohun ninu aiye wa. Ábúráhámù jẹ́ olóòtọ́ sí Ọlọ́run, eyi sí mu kí ó ni ọ̀pọ̀ ìbùkún ati òkè wa. Gbogbo èniyàn ló ń fẹ́ ìbùkún Ábúráhámù, ṣùgbọ́n má ṣe gbàgbé pé ó ti san ẹ̀tọ́ rẹ̀, san ẹ̀tọ́ rẹ loni nínú ìjọsìn rẹ, ìfọkànsìn àti ìwà mímọ́ si Ọlọ́run, nígbà náà ni ìwọ yíò ní ìdánilójú ti èso àtoke wa eyi tí ojú kò tíì rí ri tí etí kò tíì gbọ́ àti pé àwọn ènìyàn kò tíì lè fojú inú wò ó.
BIBELI KIKA: Léfítíkù 26 :3-9
ADURA: Oluwa fún mí ní ore-ọfẹ àti agbára láti rìn nínú ìlànà Rẹ ati láti pa òfin Rẹ mọ́ làti le so èso nínú aiye. Amin.