WITH FAITH, EVERYTHING IS POSSIBLE
THE SEED
Now faith is the substance of things hoped for, the evidence of things not seen. Hebrews 11:1(NKJV).
Faith has to do with believing strongly in someone or something. It can also mean having complete trust, belief, or confidence in God. In the bible, after Jesus fed the 5,000 multitude, he went to the mountain to pray, and the boat with his disciples was now in the middle of the sea with the disciples in it. Jesus walked on the sea and the disciples were afraid thinking it was a ghost, but Jesus said to them not to be afraid. Peter then asked that Jesus should command him to join Him while He walked on water, if truly, he is Jesus and not a ghost and Jesus commanded: “Come”. Then there was a wind and Peter became afraid and started sinking and Jesus said to him “O you of little faith, why do you doubt”. The woman with the issue of blood in the bible is one of the many examples of people who had faith. She said to herself “If only I may touch His garment, I shall be made well” and she touched Jesus and was healed. Her Faith made her well. Jesus told us that if we have faith as little as a mustard seed, we can tell a mountain to move and it will move. There is nothing too hard or impossible for God to do. If He can heal the sick, and raise the dead through His son Jesus Christ, he is capable of changing our problems into blessings. All we have to do is to believe and trust in Him.
BIBLE READING: Matthew 17:14-21
PRAYER: Lord, help me to trust in you completely even in the worst cases in Jesus name, Amen.
PẸ̀LÚ ÌGBÀGBỌ́ OHÙN GBOGBO NÍ ṢÍṢE.
IRUGBIN NAA
“Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ ní ìdánilójú ohun ti a nreti ijẹ́ri sí ohun ti a kó ri.” Hébérù 11:1.
Igbagbọ ni nkan lati ṣe pẹlu gbigbagbọ gidigidi ninu ẹnikan tabi nkankan. Ó tún lè túmọ̀ sí níní ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá, gbigbagbọ, tàbí ìgboya nínú Ọlọ́run. Nínú Bíbélì, lẹ́yìn tí Jésù bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ogunlọ́gọ̀ ènìyàn, ó lọ sí orí òkè láti gbàdúrà, ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wà ní àárín òkun. Jésù bá ń rìn lórí òkun, ẹ̀rù sì bà àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n rò pé iwin ni, ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe bẹ̀rù. Lẹ́yìn náà, Pétérù ní kí Jésù pàṣẹ fún òun pé kí oun dara pọ̀ mọ́ ọ nígbàtí Jésù ńrìn lórí òkun; pe bó bá jẹ́ pé lóòtọ́ ni , ti kì í sì í ṣe iwin ni, Jésù, sì pàṣẹ pé: “Wá” ẹ̀fúùfù sì wá, Pétérù bẹru o sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì, Jésù sì sọ fún un. “Ẹ̀yin o ní kékeré igbagbọ, kí ló dé tí o fi ń ṣiyèméjì.” Obìnrin tí ó ní iṣun ẹ̀jẹ̀ nínú Bíbélì jẹ́ àpẹrẹ ìkan nínú àwọn ènìyàn tí ó ní igbagbọ. O wi fun ara rẹ̀ pé “ti mo ba fọwọkan aṣọ rẹ, a o mu mi larada” bí o si ti fi ọwọ kan Jesu, a sì mú larada. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú u lára dá, Jésù sọ fún wa pé bí a bá ní ìgbàgbọ́ tó kéré bí irúgbìn músítádì, a lè sọ fún òkè ńlá kó ṣídìí láti íhìn-ín lọ sí ọhun, yíò sì ṣídi. Ko si ohun ti o le tabi ti kó ṣee ṣe fun Ọlọrun lati ṣe. Ti Ọlọrun bá lé wo aláìsàn san, ti O sí jí òkú dídé, nipasẹ ọmọ rẹ̀ Jésù Krístì; O ni agbara láti yi ìṣòro wa padà sí ìbùkún.Gbogbo ohun ti a ni lati ṣe ni, lati gbagbọ ati gbẹkẹle e.
BIBELI KIKA: Matteu 17: 14-21.
ADURA: Oluwa ran mi lọwọ lati gbẹkẹle ọ patapata, paapaa ninu awọn iṣẹlẹ ti o buru julọ ni orukọ Jesu. Amin.