THE SEED
“But He said to me, ‘My grace is sufficient for you, for my power is made perfect in weakness.’ Therefore, I will boast all the more gladly about my weaknesses, so that Christ’s power may rest on me.”
— 2 Corinthians 12:9 (NIV)
God’s power is often revealed in the places where we feel the weakest. Like the Apostle Paul, we may struggle with limitations, challenges, or personal flaws, yet God’s promise remains: His grace is enough. When we lean into our weaknesses, rather than running from them, we find that God’s strength sustains us. He takes what the world sees as weakness and turns it into a platform for His power. Our struggles become testimonies, and our challenges become opportunities for His glory to shine. Do not be discouraged by your shortcomings. Instead, allow God’s grace to carry you, knowing that His power is made perfect in your weakness.
BIBLE READING: 2 Corinthians 12:7-10 PRAYER: Lord, thank You for Your strength in my weakness. Let Your power rest on me, and let my life reflect Your sufficiency in Jesus’ name, Amen.
ÀGBÀRÁ NÍNÚ ÀÌLERA IRUGBIN NAA
“Òun sí wí fún mi pé, oore-ọfẹ mi tó fún ọ; nitori pe a sọ nítorí pé a sọ agbára mí di pípé nínú àìlera.
Nitori náà tayọ tayọ ní èmi o kúkú máà ṣògo nínú àìlera mí, kí agbára Kristi lé máà gbé inú mi”— 2 Kọ́ríńtì 12:9.
Agbara Ọlọrun nigbagbogbo n ṣe àfihàn han nibiti a ti ro pé a jẹ́ alailagbara. Gẹ́gẹ́ bi Àpọ́stélì Paulu, a le ni ìjàkadì pẹ̀lú gbedeke, ìdojúkọ tabi awọn àṣìṣe wa, sibẹsibẹ ileri Ọlọrun dúró: oore-ọfẹ rẹ to fun wa. Nigbati a bá simi lé ori awọn ailera wa, dipo ki a sá kuro lọdọ wọn, a rii pe agbara Ọlọrun n gbe wa duro. Ó gba ohun ti, aye nri bi ailera, o sí yipada si ipa agbara Rẹ. Ìlàkaká wa si di awọn ẹri, ìdojúkọ wa di anfani fun ogo Rẹ lati tàn. Má ṣé ní iporuru ọkàn nípa àwọn àṣìṣe rẹ̀. Dípò rẹ̀, gba oore-ọfẹ Ọlọrun laaye lati gbé ọ ro, ni ìdánilójú pe a sọ agbára mí di pípé nínú àìlera.
BIBELI KIKA: 2 Kọ́ríńtì 12:7-10
ADURA: Olúwa mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ fún agbára Rẹ̀ nínú àìlera mí. Jẹ́kí agbara Rẹ sinmi lé mi, ki o sí Jẹ́kí ayé mi fi tí to Rẹ han ni orúkọ Jesu, Amin.