THE SEED
By the word of the Lord the heavens were made, their starry host by the breath of his mouth. Psalm 33:6
It can be challenging to comprehend what God is doing in your life, but over time I have discovered that there are various ways we can spot His fingerprints: First, God does strong and creative activity. He wove each of us together while still within our mother’s womb. He created heaven, earth, and all living things. Then, through means of His Son Jesus, He successfully brought about everyone who places their faith in the Saviour to be saved. He also welcomed all Christians into His family. Second, by focusing our petitions on Christ and keeping them close to the Lord, we can better see God’s work. We may more easily recognise His deeds and understand how to join Him when we actively and constantly pray. Thirdly, a yielding heart can see clearly the work of God, preparing us to pay attention and follow directions. Regularly focusing on God’s Word can help us understand what the Lord is doing as well as clear our minds. Have you been preoccupied or preoccupied enough not to notice what God is doing? These items can give you a new perspective on how to see His work. Recognize your loss of focus and turn your attention back to the Lord.
PRAYER
Oh Lord, give me a yielding heart so that I can see your faithfulness towards me and also recognize your work in my life, Amen.
BIBLE READINGS: Psalm 33:3-11
DIDA ISE OWO OLORUN MO
IRUGBIN NAA
Nipa orọ Oluwa li a da ọrun, o gun irawọ wọn nipa ẹemi re. Ìwé Orin Dafidi 33:6
Ó lè ṣòro láti lóye ohun tí Ọlọ́run ń ṣe nínú ìgbésí ayé rẹ, ṣùgbọ́n bí àkókò ti ń lọ, mo ti ṣàwárí pé oríṣiríṣi onà ló wà tí a lè fi rí ìka ọwọ́ Re: Lákọ́kọ́, Ọlọ́run ń ṣe iṣẹ́ alágbára àti iṣẹ́ ìṣedá. Ó hun ẹnìkankan wa papo nígbà tí a wà nínú ìyá wa. Ó dá orun, ayé, àti gbogbo ohun alààyè. Lẹ́yìn náà, nípase Jésù Ọmọ re, ó ṣàṣeyọrí nipa fifun awọn tó bá fi ìgbàgbọ́ wọn lé Olùgbàlà láti rí ìgbàlà. Ó tún gba gbogbo àwọn Onigbagbo wọ inú ìdílé Re. Èkejì, nípa mimu be wa sinu Kristi àti Fifi wọ́n le Olúwa lowo. A le rí iṣẹ́ Ọlọ́run dáadáa. A o le da awọn iṣẹ Rẹ mọ pelu irorun. A o si loye bi a ṣe le darapọ mọ nigba ti a ba ni itara ati gbadura nigbagbogbo. Ìkẹta, ọkàn to ro mo Ọlọ́run yio ri ise oluwa kedere, ní mímúra wa síle láti kíyèsí i ,ká sì te lé àwọn ìtọ́ni. Fífiyè sí oro Ọlọ́run déédéé lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ohun tí Olúwa ń ṣe, ó sì lè mú kí ọkàn wa mọ́. Njẹ o ti gbiyanju to lati ṣakiyesi ohun ti Ọlọrun n ṣe? Awọn nkan wọnyi le fun ọ ni irisi tuntun lori bi o ṣe le rii iṣẹ Rẹ. Mọ ohun ti Iwo yi o padanu ti Iwo ko ba fokan si ise Oluwa.
ADURA
Oluwa, fun mi ni ọkan ti o Romo o ki n le rii otitọ rẹ si mi ati tun da iṣẹ rẹ mọ ninu aye mi, Amin.
BIBELI KIKA: Ìwé Orin Dafidi 33:3-11