THE SEED
On reaching the place, he said to them, Pray that you will not fall into temptation. Luke 22:40.
According to the Bible, the Holy Spirit took Jesus into the wilderness following His baptism so that He could experience the devil’s temptation there. Why, though, would God command His own Son to confront temptation? Even though He was sinless and didn’t require that symbolic purification, Jesus opted to be baptised in order to identify with the world He came to save (Matthew 3:11–13). This was just before His encounter. Then, while being tempted by Satan, He fasted for 40 days and nights in the wilderness. Jesus freely accepted this time of testing, which God allowed so that He might relate to the challenges and tribulations we all experience. But whereas many of us make mistakes and fall in to temptation, He stayed blameless despite all of Satan’s efforts. The fact that our Savior went through problems similar to those we currently experience confirms that He is aware of the difficulties His children suffer. He makes our behalf a priority while seated at God’s right hand. He willingly took on our humanity while also being entirely God and totally man. Bring your most challenging situations to Him without holding back—He genuinely understands.
PRAYER
Oh Lord, give me the grace to overcome all temptation in all situation, Amen.
BIBLE READINGS: Matthew 4:1-11
IDANWO JESU: IDOJUKO TO GA JU LO
IRUGBIN NAA
Nigbati o de ibe, o wi fun wọn pe, Ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ́ sinu idẹwò. Luku 22:40.
Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, emí Mímọ́ mú Jésù lọ sínú aginjù lẹ́yìn ìribomi re kí Ó lè rí iriri ìdánwò esu. ? Kini idi ti Ólorun yio Fi pase fun omo re lati dojuko ìdanwò? Bí ó tile jẹ́ pé kò ní eṣe tí kò sì nilo iwenumo, Jésù yàn láti ṣe ìrìbọmi láti lè dámo pelu ayé tí Ó wá láti gbala (Matteu 3:11–13). Èyí waye kí ó tó bo sinu idanwo. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Sátánì ń dán an wò, ó gbààwe fún ogójì [40] osán àti òru nínú aginjù. Jésù gba àkókò ìdánwò yìí lọ́fẹ́, èyí tí Ọlọ́run fàyè gbà kí Ó lè so Oro nípa àwọn ìpèníjà àti ìpọ́njú tí gbogbo wa ń ní. Ṣùgbọ́n níwon bí opo nínú wa ti ń ṣe àṣìṣe tí a sì ṣubú sínú ìdanwò, Ó je alailabawon pelu gbogbo igbiyanju Satani. Pe Olugbala la awon isoro ti o jomo ohun ti awa naa la koja lowolowo. Fi idi re mule wipe, Jesu mo awon isoro ti awon omo re n la koja. Ó ń fi ipò wa sí ipò àkọ́kọ́ nígbà tó jókòó ní ọwọ́ otún Ọlọ́run. O fi tinutinu gba ẹda eniyan wa nigba ti o tun jẹ Ọlọrun patapata ati eniyan patapata. Mu ipenija re ti o ga julo wa siwaju re laiboju wehin. O loye re yekeyeke.
ADURA
Oluwa, fun mi ni oore-ofe lati bori gbogbo idanwo ni ipo gbogbo, Amin
BIBELI KIKA: Mátíù 4:1-11