THE SEED
Trust in the Lord with all thine heart; and lean not onto thy understanding, in all thy ways acknowledge Him, and He shall direct thy paths. Proverbs 3:5-6.
The word of God provides profound Wisdom for making choices, we should also remember to rely on God’s guidance in making decisions not relying on man because a decision made wrongly can mar one’s future so it is better to abide by the commandment of God, putting Him first. When wondering how to ask God to make the right decisions, we can engage in prayers along with fasting and God through this can reveal the result in your dream, vision, hearing directly and lastly through prophecy. The story of Rehoboam son of King Solomon revealed how he decided to follow the advice of His peers and not the advice of the Elders to rule the Israelites instead of asking for the Wisdom of God to rule His people as done by Solomon his father. This made the Israelites revolt against him and ruling of King David’s lineage, which caused irreparable damage to the united Isreal nation till today. we shall not go astray in Jesus’ Name.
BIBLE READING: 2 Chronicles 10: 4 – 11
PRAYER: Father Lord, grant us the patience to wait and rely on you especially when we want to make decisions so we do not go astray in Jesus’ Name. Amen.
GBEKELE ỌLORUN FUN GBOGBO IPINNU RE
IRUGBIN NAA
Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹkẹle Oluwa; má si ṣe gbẹkẹle oye rẹ, jẹwọ rẹ̀ li ọ̀na rẹ gbogbo, on o si ma to ipa-ọ̀na rẹ. Òwe. 3:5-6 (KJV)
Ọ̀rọ̀ Ọlorun ń pèsè Ọgbon ijinlẹ̀ fún ṣíṣe ipinu, a tún gbodọ̀ rántí láti gbekẹ̀ lé ìtosonà Ọlorun nínú ṣíṣe àwọn ìpinnu Lai gbára lé ènìyàn nítorí ìpinnu tí a bá ṣe Lona ti ko to lè ba ọjo ọ̀la ẹni je nítorí náà ó sàn láti tẹ̀ lé àṣẹ Ọlorun, pe ki a maa fi Ọlorun se akoko. Nigbati o ba n ronu bi a se le ṣofun Ọlorun pe ki o ṣe ipinnu ti o tọ fun wa, a le gbadura pẹlu ãwẹ. Ọlọrun nipasẹ eyi le ṣafihan abajade ni ala rẹ, iran rẹ, gbigbọ taara ati nikẹhin nipasẹ asọtẹlẹ. Ìtàn Rèhóbóámù ọmọ Sólómonì Ọba fi hàn bí ó ṣe pinnu láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn ojúgbà rẹ̀, kì í sì í ṣe ìmọ̀ràn àwọn alàgbà láti ṣàkóso àwọn ọmọ Ísírelì. Dípò kí ó béèrè fún ọgbon Ọlorun láti ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ̀ gege bí Solomoni baba rẹ̀ ti ṣe. Èyí mú kí àwọn ọmọ Ísírelì ṣọ̀tẹ̀ sí i, tí won sì Tako si jíje oba ni ìdílé Dáfídì, èyí tó fa ìpalára tí kò ṣeé ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírelì tó wà níṣọ̀kan títí di òní olónìí. A ko ni sako loruko Jesu.
BIBELI KIKA: 2 Kíróníkà. 10:4-11.
ADURA: Baba Oluwa, fun wa ni suuru lati duro ati gbekele o paapaa nigba ti a ba fe se ipinnu ki a ma ba sina loruko Jesu. Amin.