THE SEED
“I planted the seed, Apollos watered it, but God has been making it grow.” 1 Corinthians 3:6
I read Paul’s words from Philippians 1. Paul was the apostle to the Gentiles. He was an unlikely eyewitness to the resurrection and one “abnormally born” into Christian service (1 Corinthians 15:8). His special calling might have made him think he was God’s army of one! But Paul knew he couldn’t fulfill his mission alone. So he built teams of fellow workers in every city he visited. While you and I often give thanks for the things God gives us, Paul gave thanks for the people God gave him to further his mission! In our text, Paul acknowledges that the teamwork of the first century involved not only himself and a gifted preacher, Apollos, but also another indispensible partner: God himself. God is the master gardener who brings about the incredible growth of his church! Ask yourself today, “What team has God put me on? With whom am I working to further the gospel?” Not even Paul could do it alone. Pray that God connects you with other believers so that in using your gifts together, you may be used of Jesus.
BIBLE READING: PHILIPPIANS 1:1-6
PRAYER: Lord, align us in your kingdom with the right people to do the job you intend for us. May your kingdom grow! Amen.
ISE AJUMOSÉ
IRUGBIN NAA
“Emi gbin irugbin, Apolo bomi rin sugbon Ọlorun ni i mu u dagba.” 1 Korinti 3:6
Mo ka awọn ọrọ Paulu lati Filippi 1. Paulu jẹ aposteli si awọn Keferi. O jẹ ẹleri ti a ko lero fun ajinde ati ẹni ti a mu wa sinu isin Kristiani ni onà ti ko ye kooro (1 Korinti 15:8). Ipe Pataki re le mu ki o ro wipe, oun je okan ninu awon omo Ogun Ọlorun ṣùgbon Poolù mo wipe oun nikan ko le se aseyori ninu irin ajo re. Torí náà, ó ko ẹgbe àwọn alábàáṣiṣe Po Jo sí gbogbo ìlú tó bá bẹ̀ wò. Lakoko ti emi ati iwọ nigbagbogbo n dupẹ fun awọn ohun ti Ọlọrun fifun wa, Paulu dupẹ fun awọn eniyan ti Ọlọrun fi fun u lati tẹsiwaju ninu isẹ iriju rẹ! Nínú ẹsẹ Ìwé Mímo wa, Poọ̀lù gbà pé kì í ṣe òun nìkan ni o le se ise Ọlorun ni àkoko naa bikose ajumose awon eniyan bii Apollo oníwàásù atí awon Olùrànlowo ti ko se e mani eyi tii se Ọlorun fúnra rẹ̀. Ọlorun ni olùtojú ọgbà tí ó mú ìdàgbàsókè àgbàyanu ti ìjọ rẹ̀ wá! Beere lọwọ ararẹ loni, “Ẹgbẹ wo ni Ọlọrun fi mi si? Ta ni mò ń bá ṣiṣe láti mú kí ìhìn rere tẹ̀ síwájú?” Paapaa Paulu ko le da sise naa . Gbadura pe ki Ọlọrun so ọ pọ pẹlu awọn onigbagbọ miiran pe ki ẹbun re le wulo fun Jesu.
BIBELI KIKA: FÍLÍPÌ 1:1-6
ADURA: Oluwa, so wa pọ ni ijọba rẹ pẹlu awọn eniyan ti o tọ lati ṣe iṣẹ ti o fẹ fun wa. Jẹ ki ijọba rẹ dagba! Amin.