GOOD, SIMPLE, STRONG WORDS
THE SEED
“Refrain from anger and turn from wrath; do not fret—it leads only to evil.” Psalm 37:8
We find many quiet but powerful words in the early verses of Psalm 37, which says “trust,” “do good,” “dwell,” “enjoy,” “delight,” “commit,” “be still,” “wait.” And all these words are used in reference to the Lord. The psalmist calls us to “trust in the LORD”; “take delight in the LORD”; “commit your way to the LORD”; “be still before the LORD”; “wait patiently for him.” And we can only “do good” in the strength of the Lord. We can only “dwell in the land” that God gives us. We can only “enjoy safe pasture” that the Lord promises and provides for us. Fretting is discouraged three times in these verses. It doesn’t take long to figure out why. When we fret, we do not trust in the Lord, we do not delight in the Lord, we do not commit our way to the Lord, we are not still before the Lord, and we do not wait patiently for the Lord. When we fret, we do not do good, we do not dwell with God, and we do not enjoy the Lord’s safe pasture. Trusting in the Lord and fretting are incompatible.
BIBLE READING: PSALM 37:1-8
PRAYER: Lord, release us from fretting for the glory of your name, for the good of others, and for our own peace. In your name we hope. Amen.
ORO RERE, TI O RORUN, TI O SI LAGBARA
IRUGBIN NAA
“Dake inu bibi, ki o si ko ikaanu sile, mase kanra ki ma baa se buburu pelu.” Orin Dafidi 37:8
A ri ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ ti o lagbara ninu awon ẹsẹ ti o ṣáájú ninu Orin Dafidi 37- “Gbẹkẹ le”, “ṣe rere”, “ma a gbe”, “Gbadun”, ‘’ṣe inu didun”, “fi le lẹ”, “dakẹ jẹjẹ”, “duro”. Gbogbo awon ọrọ wọnyii ni a nlo lati tọka wa si Ọlọrun. Oni saamu pe wa wipe ki a “Gbẹ̀kẹle Ọlọrun”, ki a ṣe “inu didun si Ọlọrun”, Ki a “fi ọna wa le Ọlọrun lọ́wọ́”, ki a dakẹ jẹjẹ niwaju Ọlọrun”, ki o si fi suuru duro de e. Ninu ipa Ọlọrun nikan ni a fi lè “ṣe rere” , a le gbe ni ile ti Ọlọrun fi fun wa, a le jẹ igbadun pápá oko tútù ati abo ti Ọlọrun ti ṣe ileri ti O si ti fi fun wa nípasẹ agbara Ọlọrun. Ọnà mẹta ní wọn ti bá ìbẹrù wí nipasẹ Bibeli yii. Eredi Rẹ ko ṣoro lati mọ. Nigbati a ba bẹrù, a ko gbẹkẹlé Ọlọrun, a ko ni inu didun ninu Ọlọrun, a ko fi ọna wa le Ọlọrun lọwọ, a ko sinmi le Ọlọrun, a ko fi suuru duro ninu Ọlọrun. Nigba ti a ba bẹrù, a ko ṣe rere, a ko ba Ọlọrun gbe, a ko si lee gbadun pápá oko tutu ati àabo Ọlọrun. Gbigbẹ -kẹle Ọlọrun ati ìbẹrù ko báramu.
BIBELI KIKA: Orin Dafidi 37: 1-8
ADURA: Oluwa, tu wa sile kuro ninu eru, fun ogo oruko re, fun rere elomiran ati fun ibale okan awa tikarawa, ninu re ni awa ni ireti. Amin