THE SEED
“I will give you a new heart and put a new spirit within you; I will take the heart of stone out of your flesh and give you a heart of flesh.” Ezekiel 36:26
The phrase ‘New Year Resolution’ is one of the most common phrases often said at the beginning of a new year. Statistically, over 80% quit their resolutions or regress within the first three months. Disappointingly, this is also true for spiritual resolutions. The mistake many people make is that they want to force a new life on a weak spiritual system. Jesus aptly describes this as ‘pouring a new wine into an old wineskin’. Brethren, there can be no meaningful change until the Spirit of the Lord works upon your heart, from where the issues of life spring from. You must receive a spirit that is conditioned to love the holy and righteous laws of the Lord.Perhaps, you want to forsake certain habits or lifestyle this year in a bid to become closer to God. Let God operate on your heart. He knows your weaknesses and imperfections and He alone can make you whole. You need yield your heart to him in prayer, fasting and consistent meditation on the word of God. He will put a new heart and a new spirit within you.
BIBLE READING: Mark 2: 18-22; Ezekiel 36: 22-38
PRAYER: Merciful Father, create in me a clean heart and renew a right spirit within me. In Jesus name. Amen
ỌKÀN TUNTUN
IRUGBIN NAA
Èmi yóò fún yín ni ọkàn tuntun, èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú yín; Èmi yóò sì mú ọkàn òkúta kúrò nínú yín, èmi yóò sì fi ọkàn ẹran fún yín. – Esekiẹli 36:26
Ipinnu odun tuntun je ohun to wọpọ ni akoko yii. Amọ, ọpọlọpọ ni ma n kuna laarin osu meta. Eyi ko tile kọ ipinnu ti èmi. Àsìse ti ọpọlọpọ n se ni wipe won fe gbe aye titun pelu ilera èmi ti ko yèkoro. Jesu pe eleyii ni ‘fifi ọtí wáìnì tuntun sínú ìgò wáìnì ògbólógbòó.’ Ará, ko le si ayipada to ni itumo, laise wipe Emi Oluwa sise lori okan eniyan, eyi tii se orisun iye. O ni lati koko gba emi ti o fe awon ofin Olorun, eyi ti n se mimo ati ododo.Boya o fe fi awon iwa atijo kan sile ti o si fe gbe igbe aye titun lati le sun mo Olorun si. Je ki Olorun se ise abe lori okan re. O mo ailera re, Oun nikan lo si le mu o lara da. O ni lati jowo emi re fun un ninu adura, awe, pelu sise asaro ninu oro Olorun nigbagbogbo. Yio si fi okan ati emi tuntun si inu re.
BIBELI KIKA: Marku 2: 18-22, Esekiẹli 36: 22-38
ADURA: Olorun Alaanu, Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, kí O sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi. Ni oruko Jesu. Amin.