BE YE NOT MOCKERS

THE SEED

Now, therefore, be ye not mockers…. Isaiah 28: 22

If for any reason you find yourself in a comfortable situation at the top, please do not make a mockery of people around you. Remember that there is a season for everything, it is your turn to be comfortable today and it shall be someone else tomorrow. God is not happy with mockers,  so children of the Most High God beware!!! tread softly and gently when it’s your turn, let us show a pure heart which is the heart of Christ in all that we do. If you are a mocker you will suffer alone. When Sarah could not conceive and she believed age was not on her side,  she pleaded and convinced her husband Abram to go in with her Egyptian maid so that she could have children through her but immediately the maid conceived,  her mistress was despised in her eyes, she started to make a mockery of Sarah and did not want to submit herself again until Sarah got angry and dealt harshly with her. Hagar had to flee from her face, she suffered, carrying a baby in her womb until an angel of God came to her rescue by instructing her to return home and submit herself to her mistress. Children of God we have to watch it, do not become a terror to your wife, husband, children, friends, workers and extended families, even to outsiders. Remember those you met when you were climbing the ladder are still the set of people you will meet when you are descending. Be good. 

BIBLE READINGS:  Genesis 16: 1 – 10

PRAYER: Dear Lord I pray for the Spirit of humility in season and out of season in Jesus Mighty Name. Amen.

 

Ẹ MÁṢE JẸ ẸLẸ́GÀN

IRUGBIN NAA

“Ǹjẹ́ nitorina, ẹ má ṣé jẹ ẹlẹ́gan..” Isaiah 28:22

Ti o ba jẹ fun idi kan, ti o ba ri ara rẹ ni ipo ọlá ni oke, jọwọ maṣe kẹgan awọn eniyan ti o wa ni ayika rẹ ti ko le gba awọn ipese bi tìrẹ.  Ranti pe akoko kan wa fun ohun gbogbo, o jẹ akoko rẹ lati wa ni ipo loni ati pe yio jẹ ti ẹlòmíràn ni ọla. Inu Ọlọ́run ko dun si àwọn ẹlẹ́gàn, fún ìdí èyí àwọn ọmọ Ọlọ́run ọga-ògo gbọ́dọ̀ ṣọ́ra wọ́n!!!  tẹ̀ ẹ jẹjẹ ki o si rọra nigbati o ba  jẹ akoko rẹ. Jẹ ki a fi ọkàn mimọ han ti o jẹ ọkan Kristi ninu ohun gbogbo ti a nṣe. Ti o ba jẹ ẹlẹgàn iwọ yió jiya nikan. Nígbà tí Sara kò lè lóyún, tí ó sì gbàgbọ́ pé ọjọ́ orí kò sí fún òun, ó bẹ Abrahamu ọkọ rẹ̀ pé kí ó bá iranṣẹbinrin ará Ejipti rẹ̀ wọlé, kí ó baà lè bímọ nípasẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn lẹsẹkẹsẹ ti iranṣẹbinrin náà lóyún, o kẹ́gàn ọga rẹ;̀.  ó bẹ̀rẹ̀ sí fi Sárà ṣẹ̀sín, kò sì fẹ́ tẹriba mọ́, títí tí Sárà fi bínú, tí ó sì fìyà jẹ ẹ́.  Hágárì ní láti sá kúrò níwájú rẹ̀, ó jìyà, pẹ̀lú ọmọ nínú rẹ̀ títí áńgẹ́lì Ọlọ́run kan fi wá gbà á níyànjú láti pa dà sílé kó sì fi ara rẹ̀ sábẹ́ ọ̀gá rẹ̀. Ọmọ Ọlọ́run a gbọ́dọ̀ Kíyèsí ara, ki ẹ maṣe di ẹrú fun iyawo yin, ọkọ, ọmọ, ọ̀rẹ́, òṣìṣẹ́,  idile yin, ati si àwọn ti ita. Ranti àwọn ti ẹ ba pade nigba ti ẹ n gun akaba si ibi gíga:wọ́n tun le jẹ́ àwọn ènìyàn ti  óò ba pade nigba ti o ba ti  n sọkalẹ. Jẹ ènìyàn dáradára. 

BIBELI KIKA: Jẹ́nẹ́sísì 16:1-10

ADURA: Oluwa mi mo gbadura fun ẹmi irẹlẹ, ni àkókò tí o wọ àti ti àkókò tí kò wọ̀ ní orukọ nla Jesu.  Amin.

Leave a comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *