COMFORT TO THE MOURNING SOUL

THE SEED

“Blessed are they that mourn: for they shall be comforted”. Matthew 5:4 (KJV)

To mourn the loss of a loved one is human nature, but one of the most difficult situations we struggle with. We came from the dust of the earth and to that dust we shall return, but this is not always so easy to accept, especially because it is not something that one can be prepared for. Mourning can also be more broadly applied to any extreme feeling of sadness or disappointment, but no matter what the situation is, we should have faith, because Jesus says He will comfort us. In a time of great difficulty, Jesus will bring calm and relief, there will be an unexplainable peace within us that could have only come from God. There will certainly be challenges we experience because we live in this world and are mortal flesh, but God will never allow us to be absorbed by sorrow or overwhelmed in distress. We are overcomers. The Psalmist says in Psalm  34 that the Lord is near the broken-hearted to comfort and heal them. There is a time to weep and mourn, but soon after, because of God’s infinite mercy and compassion, there will be a time for laughter.

BIBLE READING: Psalm34:17-19

PRAYER: Heavenly Father, even as I journey through this life and experience things that try to overwhelm me with sadness, please fill me with your peace. Holy Spirit, always be my peace, comforter and enable me to wait for my time of joy which will come in Jesus Name, Amen.

 

 

ÌTÙNÚ FÚN ỌKÀN TÍ NKÁÀNÙ

IRUGBIN NAA

“Alabukun-fun li awọn ti nkãnu: nitori a o tun wọn ninu” Matteu 5:4.

Lati ṣọfọ pípàdánù olufẹ ẹni, jẹ iriri ti o nira julọ, ṣugbọn iriri ni o jẹ́ fún ẹ̀dá ènìyàn. A wa lati inu erupẹ ilẹ, inu erupẹ yi ni a o pada si, ṣugbọn eyi ko rọrùn nigbagbogbo lati gba, paapaa nitori kii ṣe nkan ti eniyan le maa gbaradi fun. A lè lo ẹ̀dùn-ọkàn ní gbòòrò fun ìmọ̀lára ìbànújẹ́ tàbí ìjákulẹ̀ tó le koko, ṣùgbọ́n ipò  eyi yòówù kí ipò náà jẹ́, a níláti ní ìgbàgbọ́, nítorí Jesu sọ pé òun yíò tù wá nínú. Ni akoko iṣoro nla, Jesu yio mu ifọkanbalẹ ati ìdẹ̀rùn wá, alaafia ti ko ṣe e ṣé alaye yio wa ninu wa, eyiI ti o le wa lati ọdọ Ọlọrun nikan . Ó dájú pé àwọn ìpèníjà máa wà ti a bá ń gbé nínú ayé yìí, a sì jẹ́ ẹlẹ́ran ara kíkú, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí ìbànújẹ́ borí wa, tàbí kí ìdààmú bá wa. A ti ṣẹgun! Oní sáàmù sọ nínú Sáàmù 34 pé Olúwa sún mọ́ tòsí àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn láti tù wọ́n nínú àti láti mú wọn lára dá. Àkókò kan wà láti sọkún àti láti ṣọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n láìpẹ́ lẹ́yìn náà, nítorí àánú àti ìyọ́nú Ọlọ́run tí kò lópin, àkókò yió tun wà fún ẹ̀rín.

BIBELI KIKA: Orin Dafidi 34: 17-19

ADURA: Baba mi Ọrun, bi mo ṣe ń rìn irin-ajo nínu ayé yí pẹ̀lú ìlàkọjá ti o fẹ́re borí mi pẹ̀lú ibanujè, jọ̀wọ́ kun mí pẹ̀lú àlàáfíà Rẹ̀. Ẹ̀mí Mimọ máa jẹ àlàáfíà ati ìtùnú mí nigbagbogbo, Kí ó sí mú mi dúró de àkókò ayọ̀ mi tí yio de, ni orúkọ Jésù Amin.

Leave a comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *