DIVINE TOUCH 

THE SEED

“Then the LORD put forth his hand and touched my mouth. And the LORD said unto me, Behold I have put my words in thy mouth.” Jeremiah 1: 9(KJV).

The touch of God, in essence, is God’s power contacting us to influence or change our lives. God touched people in the scriptures and he continues to touch people today. One thing is sure if God touches you, your life will transform permanently. God is not mortal and does not have a physical hand. This divine touch can occur when we meditate on the word of God. We can also receive his touch when praying or when someone ministers to us. God can also touch us through vision. If you want God to touch your life, you need to have what we call FAITH and you must seek and knock. That is what the woman with the issue of blood did (Matthew 9:20). So if you believe God, he will surely intervene and touch you with his mighty hands.

No man can accomplish God’s will without being touched by him. We ought to be ready and position ourselves to receive this DIVINE TOUCH.

BIBLE READINGS:  Matthew 8:1-4

PRAYER: Father, let there be a divine touch in my soul, body and spirit in Jesus’ Name. Amen.

Friday, September 13, 2024

IFỌWỌKAN  LÁTI OKE

IRUGBIN NAA

“Oluwa sì nà ọwọ́ rẹ, o fi ba ẹnu mi, Oluwa sì wí fún mi pé, sa wo o, emi fí ọ̀rọ̀ mí sí ọ li ẹnu.” Jeremáyà 1:9

Ifọwọkan Ọlọ́run, ní pàtàkì, jẹ́ agbára Ọlọ́run ti o ńkàn sí wa, láti rú wa, tàbí yí ìgbésí ayé wa padà. Ọlọ́́run fọwọ́ kan àwọn ènìyàn nínú àwọn ìwé mímọ́, tí ó sì ń tẹsiwaju láti fọwọ́ kan àwọn ènìyàn bakannaa lónì. Ohun kan dájú pé tí Ọlọ́run bá fọwọ́ kan ọ, ayé rẹ yíò yí padà pátápátá. Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, àti pé kò ni ọwọ ti a lé fi ojú rí. Ifọwọkan atọrunwa le waye nigba ti a ba nṣe àṣàrò lori ọ̀rọ̀ Ọlọrun,  A tun le gba ifọwọkan rẹ nigbati a ba ngbadura tabi nigbati ẹnikan ba nṣe iṣẹ iranṣẹ fun wa.  Ọlọrun tun le fi ọwọ kan wa nipasẹ iran. Tí o ba fẹ ki Ọlọrun fi ọwọ kan aye rẹ o nilo lati ni ohun ti a n pe ni igbagbọ, ati pe o gbọdọ, wa kiri ati ki o kan ilẹ̀kùn. Èyí ni ohun ti obinrin ti o ni ìsun ẹ̀jẹ̀ ṣe ninu iwe (Matteu 9 ẹsẹ 20) Nitorinaa ti o ba gbagbọ Ọlọrun yíò dasi ọ̀rọ̀ aye rẹ, dajudaju yíò fi ọwọ kan ọ pẹlu ọwọ agbara Rẹ. Kò si eniyan ti o le ṣe ifẹ Ọlọrun laisi ifọwọkan Rẹ̀. A nílò láti ṣe tan ki a sí gbaradi láti gba ifọwọkan atoke  wá yi.

BIBELI KIKA: Matteu 8: 1-4

ADURA:  Baba jẹ ki ifọwọkan atoke,0 fi ọwọ kan ọkàn, ara ati ẹmi mi ni orukọ Jesu Amin.

Leave a comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *