THE SEED
But be ye doers of the word, and not hearers only, deceiving yourselves. James 1:22(KJV)
To become the doers of the word means obeying God’s commandments and adhering strictly to them, without moving or looking to the left or right. We can achieve these through studying the Word of God to get intimated with Him, knowing all that He demands from us as man, and praying to communicate with Him without ceasing. Then His spirit will come to dwell in us and guide us to become the doer of the word. It is not the hearers of the law who are righteous before God, but those who read the Word, meditate on the Word and apply it to your daily lives because it’s only the doers that will be justified Romans 2:13. Furthermore, the doers of the word will always be ready to seek for the truth and when he finds it he will apply to his life and he will become a new creature, for old things have passed away. Hearers only listen to Know the Word but never live with it, Doers on the other hand listen, know and obey it to the letter. So brethren pray for the Power of the Holy Spirit to empower you to overcome the flesh, to interpret God’s Words to you, and most especially to open your understanding for the Word, to be the hearer and the doer of the Word in order not to deceive yourself.
BIBLE READINGS: Matthew 7: 21 – 27
PRAYER: O Lord, help us to be the doer of your word and not the hearer alone in Jesus’ Name. Amen.
OLÙṢE Ọ̀RỌ̀ NÁÀ
IRUGBIN NAA
“Ṣùgbọ́n kí ẹ jẹ́ olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kí o ma si ṣé olugbọ nìkan, ki ẹ ma tàn ara yín jẹ.” Jákọ́bù 1: 22
Láti jẹ́ olugbọ ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ si gbigbọran si awọn ofin Ọlọrun ati titẹ ramọ wọn ni pipe, lai má mọ gbogbo ohun ti o beere lọwọ wa gẹgẹbi eniyan, ati gbigbadura lati ba a sọrọ lai sinmi. Lẹhinna ẹmi Rẹ yíò wa lati gbe ni inú wa, yíò ṣe itọsọna fun wa lati di olùṣe ọ̀rọ̀ náà. Kii ṣe awọn olugbọ ofin náa ni o jẹ olododo niwaju Ọlọrun, ṣugbọn awọn ti o ka ọrọ naa, ti wọ́n nṣe àṣàrò lori ọrọ naa, wọn si nfi sinu igbesi aye wọn lojojumo. Nítorí pé àwọn olùṣe ọ̀rọ̀ náa nikan ni ao dalare Romu 2:13. Pẹlu pẹlu awọn olùṣe ọ̀rọ̀ naa yoo maa mura lati wa otito nigba ti wọn ba rii yíò darapọ mọ́ igbesi aye wọn, wọ́n yíò sí di ẹda tuntun, nítorí ohun atijọ ti kọja lọ. Olugbọ nikan ni o ngbọ ati lati mọ ọrọ naa ṣugbọn ko gbe pẹlu rẹ. Awọn olùṣe ni ọna kejì, mọ̀, wọ́n sí fetisilẹ, wọ́n si jẹ olugbọ́ràn si awọn ọ̀rọ̀ náa pátá pátá. Nítorí náa ara, gbadura fun agbara ti ẹmi mimọ lati fun ọ ni agbara lati bori ẹran-ara, lati tumọ awọn ọrọ Ọlọrun fun ọ ati paapaa julọ lati ṣí oye rẹ si ọrọ naa láti lè jẹ olugbọ́ ati olùṣe ọrọ náa, ki o ma ba tan ara rẹ jẹ.
BIBELI KIKA: Matteu 7:21- 27
ADURA: Oluwa ran wa lọ́wọ́ ki a le jẹ olùṣe òrọ̀ Rẹ̀, ki ìṣe olugbọ nìkan lórúkọ Jesu Amin