FAITH THAT HEALS

THE SEED

‘When Jesus heard it, he marvelled, and said to them that followed, Verily I say unto you, I have not found so great faith, no, not in Israel.’ Matthew 8:10 KJV

When we wholeheartedly trust God, healing takes place through faith. In this context, healing does not necessarily mean a cure from illness alone but could also be deliverance from any crises such as financial issues, making better sales, stagnancy, emotional issues, or anything that does not feel right. While we Christians believe that Jesus Christ paid the price for all of our sins, how much do we trust God when things don’t work out as planned? As believers, we can demonstrate our faith in God when confronted with obstacles in life by trusting God totally, and laying hold on the promises in the word of God to claim it for the situation, we must also exercise our faith in consistent Prayer and patiently wait on directions or guidance from Him, we be wary of any advice that is contrary to the Bible and finally, executing actions to overcome such challenge just like the woman with the issue of blood, she took action to move and touch Jesus. God is interested in our faith, particularly when we experience unfavourable circumstances in life, from the smallest challenge to the most significant issues. God is always willing to assist us, no matter what the problem may be but our faith has to play its role. Our faith will guide us to overcome obstacles.

BIBLE READING: Mark 5: 25-34

PRAYER: Oh lord, let my trust in you bring forth healing in all situations of my life. Amen.

 

 

 ÌGBÀGBỌ́ TÍ Ó NWO SÀN.

IRUGBIN NAA

“Nígbàtí Jésù gbọ, ẹnu ya a, o si wi fún àwọn ti o ntọ lẹ́hìn pé, Lootọ ni mo wí fún yín, èmi kó rí igbagbọ ńlá bí irú èyí nínú awọn eniyan Israeli”. Matteu 8:10.

Nigba ti a ba gbẹkẹle Ọlọrun tọkàntọkàn, iwosan maa nwaye nipasẹ Igbagbọ. Ninu abala yii, iwosan ko tumọ si ìmúláradá nipa aisan nikan ṣugbọn o tun le jẹ itusilẹ kuro ninu idaamu eyikeyi gẹgẹbi awọn ọrọ iṣuna-owo, a ta jèrè ọjà, idaduro, ẹdun okan, tabi ohunkohun ti ko lọ déédéé. Nigbati awa kristeni gbagbọ pe Jesu Kristi san gbèsè fun gbogbo ẹṣẹ wa, báwo ni igbẹkẹle wa nigbati awọn nkan ko ri bi a ti pinnu? Gẹgẹbi onigbagbọ a le ṣe afihan igbagbọ wa, ninu Ọlọrun nigbati a ba koju awọn idiwọ lọ́nà wa, nipa gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun patapata, ati di di awọn ileri ti o wa ninu ọrọ Ọlọrun mu, fun iborí iru ìdojúkọ naa, a tun gbọdọ lo igbagbọ wa ninu Adura gbígbà deede, ki a si fi suuru duro de awọn idari tabi itọsọna lati ọdọ Rẹ. Ki a ṣọra fun imọran eyikeyi ti o lodi si Bibeli ati nikẹhin, ṣíṣe awọn iṣe lati bori iru ipenija bẹẹ Gẹ́gẹ́bí obinrin ti o ni ìsun ẹjẹ ti o gbe igbesẹ lati fọwọkan Jesu. Ọlọrun nifẹẹ ninu igbagbọ wa paapaa, nigba ti a ba ni iriri awọn ayidayida ti ko dara ninu aye, lati ipenija ti o kere julọ si awọn ohun ti o ṣe pataki julọ. Ọlọ́run máa ń múra tán láti ràn wá lọ́wọ́ láìka ìṣòro yòówù kó jẹ́ ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ wa ní láti kó ipa tirẹ̀, Ìgbàgbọ́ wa yóò tọ́ wa sọ́nà láti borí àwọn ohun ìdènà.

BIBELI KIKA: Máàkù 5:25-34.

ADURA: Oluwa, jẹ́ ki ìgbẹ́kẹ̀lé mi le mu iwosan jade ni gbogbo ìdojúkọ ninu aye mi. Amin.

Leave a comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *