THE SEED
”Be kind to one another, tenderhearted, forgiving one another, as God in Christ forgave you.“ Ephesians 4:32 ESV
The above scripture encourages us that in God’s forgiveness of our sins, we should also be inspired to forgive others with the same compassion and love we have received from God. There is an amazing parable told by Jesus to this effect in the book of Matthew chapter 18. The life of some followers of Christ can be related to the unforgiving servant in the parable. He displayed a high level of ungratefulness when he dealt mercilessly with his fellow servant who owed him little after his master had forgiven him the huge debt he owed him. The significance of this parable to us is that each time we refuse to forgive our fellow brethren for their wrongs towards us, we are certainly telling God who forgave our huge sins that we are ungrateful. The intention of God is for us to learn from Him and have the willingness of heart to forgive anyone who offends us.
BIBLE READINGS: Matthew 18:23-30
PRAYER: Lord I pray, please release a forgiving spirit upon me, let me find it easy to forgive people that offend me, in Jesus’ name. Amen
DARIJI GEGE BI A TI DARIJI O
IRUGBIN NAA
“Ẹ je onínúure sí ara yín, ẹ je olokan tutu, ẹ máa dáríji ara yín, gege bí Ọlọrun ti dáríjì yín nínú Kristi.” Efesu 4:32
Ẹsẹ Ìwé Mímo tó wà lókè yìí gbà wá níyànjú pé nínú ìdáríjì Ọlorun, a tún gbodọ̀ ní ìmísí láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú ìyonú àti ìfe kan náà tí a ti rí gbà látọ̀dọ̀ Ọlorun. Owe àgbàyanu kan wà tí Jésù sọ nípa èyí nínú ìwé Mátíù orí 18. Ìgbésí ayé àwọn ọmọleyìn Kristi ní í ṣe pẹ̀lú ìránṣe tí kò dárí jini nínú owé náà. O se afihan iwa aimoore nígbà ti ko saanu fun ore re ti o je ni oun kekere lehin igba ti Oga re ti dari gbese nla re ji. Pataki owe yii fun wa ni pe nigbakugba ti a ba kọ lati dariji awọn arakunrin ẹlẹgbẹ wa fun aiṣedede wọn si wa, dajudaju a n sọ fun Ọlọrun ti o dariji awọn ẹṣẹ nla wa jì wa pe a jẹ alaimoore. Ife Ọlorun ni pé kí a kekọ̀o lodọ̀ rẹ̀, kí a sì ní ìmúratán ọkàn láti dárí ji ẹnikeni tí ó bá ṣẹ̀ wá.
BIBELI KIKA: Mátíù 18:23-30
ADURA: Oluwa mo gbadura, jowo tu emi idariji sori mi, je ki o rorun lati dariji awon eniyan ti o semi ni oruko Jesu. Amin