THE SEED
“But God will never forget the needy; the hope of the afflicted will never perish.” Psalms 9:18 NIV
In Psalms 9:18, we find a great assurance of God’s unfailing love and care for the needy and afflicted. The verse serves as a comforting reminder that no matter how threatening our circumstances may seem, God is always aware of our struggles and stands as a beacon of hope during challenges. Life’s journey often brings us to moments of hardship and difficulty, where we may feel forgotten and alone. Yet, in these times of distress, God’s promise in Psalms 9:18 becomes a source of strength. He never forgets those who are in need or afflicted. His heart is tender towards the brokenhearted, and His eyes are fixed upon those who are hurting. As we encounter challenges and witness the struggles of others, let us be a reflection of God’s love and hope. Let us extend a helping hand, lend a listening ear, and offer prayers for those in need. In doing so, we become instruments of God’s compassion, spreading His hope to the hurting. Beloved, it is refreshing to find relief in knowing that God will never forget the needy and that the hope He provides to the afflicted will never perish.
BIBLE READINGS: 72:12-14
PRAYER: In times of trial, let me be able to draw myself and others near to you Lord, knowing that your love and hope are ever-present in our lives, in Jesus’ name. Amen
ỌLỌ́RUN JẸ́ IRETÍ LAILAI FÚN ÀWỌN ALÁÌNÍ
IRUGBIN NAA
Nítorí pé Olúwa ki yíò gbàgbé awọn aláìní láìláì ìrètí àwọn tálákà ki yíò ṣègbé lailai.” Psalm 9:18.
Nínú Orin Dafidi 9: 18 a rí ìdánilójú ńláǹlà ti ìfẹ́ Ọlọ́run tí kìí ja nikulẹ ìtọ́jú àwọn aláìní àti àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́. Ẹsẹ Bíbélì náà ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí ìtùnú pé láìka bí àyíká ipò wa ti lè halẹ̀ tó. Ọlọrun nigbagbogbo mọ ti awọn ijakadi wa, o si duro bi ai yipada ireti lakoko awọn wàhálà wa. Irin-ajo igbesi aye mu wa lọ si igbe aye ti inira ati iṣoro, nibiti a le ni èrò pé a gbàgbé wa tí o sí jẹ àwa nikan. Síbẹ̀ ní àkókò wàhálà, ìlérí Ọlọ́run nínú Sáàmù 9:18 di orísun agbára. Kò gbàgbé àwọn tí wọ́n wà nínú áìní tàbí àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́. Ọkàn rẹ̀ rọ̀ sí àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn, ojú rẹ̀ sì tẹ̀ mọ́ àwọn tí a ńṣe ni ìṣẹ́. Bí a ṣe ń bá àwọn ìpèníjà pàdé tí a sì ńwo ila kaka àwọn ẹlòmíràn, jẹ́ kí a jẹ́ àfihàn ìfẹ́ àti ìrètí Ọlọrun. Ẹ jẹ́ kí a na ọwọ́ ìrànwọ́, ki a ni ifarabalẹ làti tẹ́tí gbọ́ ẹdùn ọkàn oníròbìnújẹ́, kí a sì gbadura fún àwọn tí ó ṣe aláìní. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di ohun èlò ìyọ́nú Ọlọ́run tí ń tan ìrètí Rẹ̀ kalẹ̀ fún àwọn aláìní. Olùfẹ́, ó ntù ni lára láti rí ìtura, ní ìdánilójú pé Ọlọ́run kì yóò gbàgbé àwọn aláìní láé àti pé ìrètí tí Ó pèsè fún àwọn tí a ń ṣẹ́ ni ìṣẹ́ kì yóò ṣègbé láé.
BIBELI KIKA: Psalm 72 : 12 – 14
ADURA: Ni akoko idanwo jẹ ki n le fa ara mi ati àwọn ẹlòmíràn sunmọ ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Olúwa mi mo mọ pe ìfẹ́ Rẹ̀ àti ìrètí Rẹ̀ wa nínú wa ni igbagbogbo lórúkọ Jesu. Àmín