GOOD SUCCESS

GOOD SUCCESS

THE SEED

“This book of the law shall not depart out of thy mouth, but thou shalt meditate therein day and night, that thou mayest observe to do according to all that is written therein: for then thou shalt make thy way prosperous, and then thou shalt have good success” Joshua 1:8.KJV

Good success? Does that mean that there is bad success? This shows that good success comes from God to his people, when we look at Proverb 10:22 (The blessing of the Lord, it maketh rich, and he addeth no sorrow with it)this shows that sorrow too can be in riches. There are different kinds of success in our generation, people seek breakthroughs for riches from different sources,with conditions. So many people have died untimely and lost precious things and their loved ones, because they have bad success. God promised us good success when we meditate in His word and abide in it, He will bless the works of our hands and we will sit with Kings and not mean men. Good success also comes with peace of mind, prosperity, and a lot of good things. God gives this only to His beloved, who obey Him and follow His commandments, He will be their God and they shall be His people.

BIBLE READING: Joshua 1:1-9

PRAYER: Oh Lord, I pray you give me success, help me to believe and abide in you, Amen.

 

 

ÀṢEYỌRÍ TO DÁRA

IRUGBIN NAA

“Ìwé òfin yi ko gbọdọ kúrò ní ẹnu rẹ, ṣùgbọ́n kí ìwọ o maa ṣè àṣàrò nínú rẹ̀ ni ọ̀sán àti ní òru, ki ìwọ kí ó lé Kíyèsí àti ṣè gẹ́gẹ́ bi gbogbo eyítí a kọ sínú rẹ̀: nitori nigbana ní ìwọ o ṣé ọ̀nà rẹ ní réré, nigbana ni yío sí dára fún ọ.” Jóṣúà 1:8.

Aṣeyọri to dara? Njẹ eyi tumọ si pe aṣeyọri buburu wa? Èyí fi hàn pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àṣeyọrí réré máa ti nwa sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Rẹ̀, nígbàtí a ba wo ìwé Òwe 10:22 (Ìbùkún Olúwa ni n sọ ni di ọlọ́rọ̀, ti ki sì i fi laa laa kún un) èyí fi hàn pé ìbànújẹ́ pẹ̀lú lè wà nínú ọrọ̀. Awọn oriṣiriṣi aṣeyọri ni o wa ninu iran wa, awọn eniyan n wa awọn aṣeyọri fun awọn ọrọ̀ ni gbogbo ọ̀nà, èyí sí wà pẹlu awọn àlàkálẹ̀ oríṣiríṣi. Ọ̀pọ̀ èniyàn ló ti kú lái to àkókò, tí wọ́n sì pàdánù àwọn ohun iyebíye gẹ́gẹ́ bí olólùfẹ́ wọn nítorí pé wọ́n ní àṣeyọrí burúkú. Ọlọrun ṣe ileri aṣeyọri réré fun wa nigba ti a ba ṣe àṣàrò ninu Ọ̀rọ̀ Rẹ, ti a si duro ninu rẹ; yíò bukun awọn iṣẹ ọwọ wa ati pe awa yíò joko pẹ̀lú awọn ọba, kii ṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn lasan. Àṣeyọrí réré máà ńwá pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn, aásìkí ati pẹ̀lú ohun dáradára gbogbo. Ọlọ́run ń fún àwọn ayanfẹ Rẹ̀ níkan ní nkan wọ̀nyí, àwọn tí wọ́n bá ń gbọ́ tirẹ̀ , tí wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òfin rẹ̀, òun ni yíò jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yíò sì jẹ́ ènìyàn rẹ̀.

BIBELI KIKA: JOṢUA 1: 1-9.

ADURA: Oluwa!, Mo gbadura pe Ìwọ yíò fun mi ni aṣeyọri, ran mi lọwọ lati gbagbọ ati lati gbe inu Rẹ, Amin.

Leave a comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *