Let Us Pray One For Another

THE SEED
And for me, that utterance may be given to me, that I may open my mouth boldly to make known the mystery of the gospel. Ephesians 6:19

It is so important that we, the church, function as the body of Christ. By being “members of one another,” we can efficiently sustain each other and even intercede or “stand in the gap before God on behalf of” our brothers and sisters in Christ. The Apostle Paul had not asked the churches to pray for him personally, but for his Ministry, so that even more people would be saved and start to live right for God. The Apostle Paul’s Ministry was full of power and through the epistles he wrote, inspired by the Holy Spirit, he has continued to bless Christians throughout all times. We all need the prayers of our brothers and sisters in Christ for God’s help to share the Good News of salvation through Jesus Christ. When we pray one for another, the love and unity grow in the body of Christ and God’s Kingdom expands.

BIBLE READING: GALATIANS 6

PRAYER: Dear Lord please help me to live right, so that people will see You in me. Holy Spirit, please help me to be sensitive when You direct me to pray for others and teach me how to pray efficiently in the Name of Jesus. Amen.

ẸJẸ KI A GBÀDÚRÀ FUN ARÁ WA.

IRUGBIN NAA
Ati fun mi, ki a le fifun mi, ki emi ki o le fi igboiya ya ẹnu mi lati sọ ohun ijinlẹ ihinrere di mímọ, Efesu 6:19

O ṣe pataki pupọ pe awa ijọ, gbọdọ ṣiṣẹ bi ara kan ninu Kristi. Nípa jíjẹ́ “ẹ̀yà ara kan na larin ẹ́nì kìíní si kejì,” a lè gbé ara wa ró dáradára, ká sì máa gbàdúrà tàbí “dúró nínú àlàfo tí o wa níwájú wa àti Ọlọ́run nítorí” àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nínú Kristi. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kò sọ fún àwọn ìjọ pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún òun fúnra rẹ̀, bí kò ṣe fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, kí àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lè ní ìgbàlà, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé tó tọ́ fún Ọlọ́run. Iṣẹ́-òjíṣẹ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kún fún agbára àti nípasẹ̀ àwọn lẹ́tà tí ó kọ sí àwọn ìjọ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, ń tẹ síwáju láti máa bùkún àwọn Kristẹni ní gbogbo ìgbà. Gbogbo wa nilo adura awọn arakunrin ati arabinrin wa ninu Kristi fun iranlọwọ Ọlọrun lati pin ihinrere igbala nipasẹ Jesu Kristi. Nígbà tí a bá ń gbàdúrà fún ara wa, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ndàgbà nínú ara Kristi àti Ìjọba Ọlọ́run.

BIBELI KIKA: Galatia 6

ADURA: Oluwa mi, jọwọ ran mi lọwọ lati gbe igbe ododo, ki awọn eniyan ki o le ri Ọ ninu mi. Ẹmi Mimo, jọwọ ran mi lọwọ lati ni imọ lára nigba ti O ba dari mi lati gbadura fun awọn elomiran, ki o si kọ́ mi bi mo ṣe le gbadura daradara ni Orúkọ Jesu. Amin.

 

Leave a comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *