THE SEED
“That you also aspire to lead a quiet life, to mind your own business, and to work with your hands, as we commanded you.” – 1 Thessalonians 4:11 (NIV)
With social media at our fingertips, it’s easy to become overly interested in other people’s lives. Some go further, spreading rumors or speaking badly about others, often without knowing the truth. God calls us to be different. We should focus on our own lives, avoiding gossip and minding our words. Let’s not entertain or spread unkind conversations about others. Instead, if we hear anything negative, let’s respond with prayer, asking God to work for good in that person’s life.
BIBLE READING: Ephesians 4:31-32
PRAYER: Lord, help me to refrain from gossip and speak only words that build others up. Guard my heart and mind so that I may focus on living a life pleasing to You. Amen.
GBỌ TÍ ARA RẸ
IRUGBIN NAA
“Àti pé kí ẹ̀yìn kí ó máà du u gidigidi láti gbé jẹ́, láti máà gbọ tí ará yín, kí ẹ maa fí ọwọ́ yin ṣíṣe, gẹ́gẹ́ bí àwa ti pàṣẹ fún yín”. Tẹsalóníkà kíni 4: 11.
Pẹlu awọn ọ̀rọ̀ ti o nlọ lori ẹ̀rọ alagbeka wa, o rọrun lati nifẹ pupọ ninu áwọn ohun tí o nlọ nínú igbesi aye awọn eniyan miiran. Diẹ tẹ̀siwaju, nipa titan áwọn ọ̀rọ̀ gbogbo ti kó ni otitọ nínú, tabi si sọ ọ̀rọ̀ buburu nipa awọn miiran, nigbagbogbo lai mọ otitọ. Ọlọrun pè wa lati yatọ. O yẹ ki a fojusi si igbesi aye tiwa, yago fun ofofo ki a kíyèsí awọn ọrọ wa. Ẹ má ṣe jẹ́ ká máa bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, tí a bá gbọ́ ohun tí kò dára nípa ẹnìkan, ẹ jẹ́ kí a dáhùn pẹ̀lú àdúrà pé kí Ọlọ́run ṣiṣẹ́ rere nínú ìgbésí ayé ẹni náà.
BIBELI KIKA: Éfésù 4: 31-32
ADURA: Olúwa ràn mí lọwọ láti yàgò fún ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, kí èmi kí ó lé máà sọ kìkì ọ̀rọ̀ tí ó ngbé ní ró. Sọ ọ̀kan atí àyà mí ki èmi kí ó lé máa ní àfojúsùn nípa gbígbé ìgbé ayé tí ó wù Ọ. Amin.