PRAYER OF FAITH

THE SEED
‘And the prayer of faith shall save the sick, and the Lord shall raise him; …’. James 5: 15

PRAYER is the most sincere way that we communicate with God. It is an action that connects our spirits to God’s, just as energy to our being. PRAYER is not just that, it is also the master key to every situation in our lives, regardless of how tiny or significant the issue is. But what happens when we pray without believing? We are like a double-minded man who is unstable in all his ways. Even the bible tells us not to think that a man who asks while wavering shall receive anything from the Lord. Faith in prayers is very essential. It is not about how many times we pray, but how much trust we put in God when we say our prayers.  Usually, when we ask our loved ones for something, probably a gift, and then say, we are not sure if they are capable of giving your request. Likewise, when we ask from God without faith, it shows that we are not ready to receive from him.  Faith in prayers is not just an affirmation, it is knowing and holding in your heart that what God says he will do, that is what he will do. No matter how long or delayed it may seem, the thought he has for us is to give us an expected end. He said that when we pray, he will hearken to us, that’s a promise. Therefore, even in the slightest of things, whatever it might be, let us ask of God, believing that he gives freely, without criticism, and it shall be granted.

BIBLE READINGS:  James 5: 13-18

PRAYER: Oh Lord, help me to pray in faith without wavering, that I may receive my heart requests in Jesus’ name, Amen.

 

ÀDÚRÀ ÌGBÀGBỌ́

IRUGBIN NAA

Adura igbagbọ yíò si gbá aláìsàn náà la, Oluwa yíò sí gbe e dìde: bi o ba sí ṣe pé o ti dẹ́ṣẹ̀,  a o dari ji i. Jákọ́bù 5:15.

Adura jẹ ọna otitọ julọ lati ba Ọlọrun sọrọ. O jẹ iṣe ti o so ẹmi wa pọ mọ ti Ọlọ́run, gẹgẹ bi agbara si ẹ̀dá wa. Adura ko wa lasan, o tun jẹ kọ́kọ́rọ́  si gbogbo iporuru ninu igbesi aye wa, laibikita títóbi tabi kíkéré idanwo náà. Ohun ti o ṣe pataki julọ ni pé kini o mṣẹlẹ nigbati a ba ngbadura laisi igbagbọ?  A dabi ọkunrin oniye meji ti ko duro ni gbogbo ọna rẹ. Bíbélì paapaa  sọ fun wa pe ki a ma ronu pe ọkunrin ti o beere pẹ̀lú iye meji yíò  ri ohunkohun gba lọwọ Oluwa. Igbagbọ ninu adura jẹ pataki pupọ. Kii ṣe nipa iye igba ti a ngbadura, ṣugbọn bawo ni igbẹkẹle wa nínú Ọlọrun nigba ti a ba n gbàdúrà. Nigbagbogbo nigbati a ba nbeere ohun kan lọwọ awọn ololufẹ wa,  boya ẹbun kan ni, lẹhinna ti a si sọ pe, a ko ni idaniloju boya wọn lagbara lati fun wa.  Bákan náà nígbà tí a bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láìsí ìgbàgbọ́, ó fi hàn pé a kò ṣe tán láti ri gba lọ́dọ̀ Rẹ̀. Ìgbàgbó ́ nínú àdúrà kìí ṣe ìmúdánilojú lásán, eyi jẹ mí mọ pe, atí ìmú lọ́kàn le pé ohun tí Ọlọ́run sọ pé Òun yíò ṣe. Bi o ti wu ki o ṣe pẹ to tabi ki idaduro le wa, ero ti o ni fun wa ni lati fun wa ni opin ti o nireti. O sọ pe nigba ti a ba gbadura pe oun yíò tẹ̀ ti si wa eyi jẹ ileri.  Ohunkohun ti o le jẹ,  ki a beere  li ọwọ Ọlọ́run pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pe o nfi funni lọfẹ laisi ìbáwí ao si fun wa.

 

BIBELI KIKA: Jakobu 5:13-18

ADURA: Oluwa ran mi lọ́wọ́ lati gbadura pẹ̀lú igbagbo lai ṣe iyemeji ki n le gba ibere ọkàn mi lórúkọ Jesu Amin

Leave a comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *