THE SEED
“I know that whatever God does, It shall be forever..” Ecclesiastes 3:14 NKJV
What can we do without God’s creation? The answer is ‘absolutely nothing’! According to the opening scripture, nothing can be added to God’s creation and nothing can be taken away from it, this includes the beautiful life He has given to you. Yes, things have been made by humans from God’s creation but we should always know that without the creation from God, there will be no raw materials for man’s innovation. Given this, we ought to pay homage to our Father in heaven for the endowment of His creation for our use. As we continue our devotion, let’s take a moment to be grateful for the magnificent creations around us. The heavens and the earth are handcrafted by our Creator. From the free air we breathe in and out, to the breathtaking sunrise to the beautiful sunset that gives us the privilege to go about our daily activities and have a rest from our labour, the different seasons that give us the ability to plant and harvest food to sustain life in us and the numerous trees and unquantifiable sands that fill the earth which become our raw materials for building the house we live in, is a masterpiece that can not be compared to none. Beloved of Christ, just take a moment of each day that you are privileged to witness and say thank you, God, for your amazing creation.
BIBLE READINGS:Psalm 95:3-7
PRAYER: Lord, give me the understanding to be thankful for your amazing creation. Amen
ỌPẸ́ FÚN ÌṢẸ̀DÁ RẸ̀
IRUGBIN NAA
“Emi mọ̀ pé ohunkohun ti Ọlọrun ṣe tí yió wà títí lae… Oniwasu 3:14
Láìsí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run, kíni a le ṣe? Ídáhùn rẹ ni pé kò sí ohun tí a le ṣe! Ni ìbámu pẹ̀lú ẹsẹ, ìwé Mímọ́ tí ó bẹ̀rẹ̀, kò sì ohun tí a lè fi kún ìṣẹ̀dá Ọlọ́run, kò sì ohun tí a lè mú kúrò nínú rẹ̀, èyí sì pẹlú iwàláàyè ẹlẹ́wà tí ó ti fi fún ọ. Bẹni àwọn ohun kàn wa ti a tí ọwọ eniyan ṣe lati ara ohùn tí Ọlọrun da; ṣùgbọ́n kí a mọ̀ nígbà gbogbo pé láìsí ìṣẹ̀dá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kì yíò sí ohun àmúlò fún àtúnṣe ènìyàn. Pẹlu ohun tí a fún wa yíi, ẹ jẹ́ kí a ya àkókò díẹ s’ọ́tọ̀ láti fí ìmoore hàn fun bàbá wá ní ọrùn nípa fí fún wa ni ìṣẹ̀dá yíi fún ìlò wa. Bi a tí ṣe nlọ nipa awọn ìsìn wà, ẹ jẹ́ki a ni akoko fún ìmọ, riri agbayanu iṣẹ̀da ní àyíká wa. Ọ̀run àti ayé jẹ iṣẹ ọwọ ẹlẹdà. Láti ọdọ àtẹgun ọ̀fẹ́ tí a nmì sínú, mi sí ìta, titi dé ọ̀dọ̀ ìlà oòrùn dé ìwọ̀ oorun tí o ní ẹwà; èyí tí o nfun ni, ni anfaani lati lọ sí ìbi iṣẹ ojoojumọ wa ati lati le ni isinmi kúrò lẹnu iṣẹ wa. Awọn akoko oriṣiriṣi ti o fun wa ni agbara lati gbin ati lati koore ounjẹ, lati ṣe itọju igbesi aye wà; ati awọn igi lọpọlọpọ ati ainiye erupẹ tí o wà ni orilẹ ayé tí o dúró fún èròjà ikọ́le tí à ngbe nínú rẹ. Èyí jẹ́ ohùn tí kò ṣe é fi wé ohunkohun. Olufẹ Kristi, mu iṣẹju diẹ ni ọjọ kọọkan ti o ni anfani, fún ẹrí lati sọ pé mo dupẹ lọwọ Ọlọrun, fun àgbàyanu ẹda iṣẹ ọwọ Rẹ̀.
BIBELI KIKA: Psáàmù 95:3-7
ADURA: Oluwa, fun mi ni oye lati dupẹ fun àgbàyanu awọn ẹda iṣẹ ọwọ RẸ. Amin.