THE SEED
“Jesus was angry as he looked around them, but at the same time he felt sorry for them because they were so stubborn and wrong…” Mark 3:5 GNT
Anger itself is not wrong. It depends on what makes us angry and what we do with our anger. Anger directed at sin and maltreatment of others is not wrong. When injustice or sin makes you angry, ask God how you can constructively channel that anger to help bring about positive change. Too often we express our anger in selfish and harmful ways. We need to emulate Jesus who expressed His anger by correcting a problem. Therefore, use your anger to find constructive solutions rather than tearing people down. One other thing about this type of anger is that it is not directed at people but at what is being done wrong, in verse 5 of the
BIBLE READING: Mark 3:1-5
PRAYER: Father in the name of Jesus let your Spirit teach me to handle anger constructively and acceptably in your sight. Amen
IRU IBINU TI O SE ITẸWOGBA
IRUGBIN NAA
Jésù bínú bí ó ti ń wò yí wọn ká, ṣùgbon ní àkókò kan náà, ó ṣàánú wọn, nítorí won ṣe agídí àti àìto. Máàkù 3:5-11
Ibinu funrararẹ kii ṣe oun ti o lodi. O da lori ohun ti o mu wa binu ati ohun ti a ṣe pẹlu ibinu wa. Ìbinu ti a Fi dojuko ese atí ifiyajeni Lona àìto ki se oun ti o lodi. Nigbati aiṣododo tabi ẹṣẹ ba mu ọ binu, beere lọwọ Ọlọrun bi o ṣe le dari ibinu re si onà ti yio mu iyipada rere wa. Lopọ̀ ìgbà a máa ń fi ìbínú wa han lonà ìmọtara-ẹni-nìkan àti àwọn ọ̀nà ìpalára. A ni Lati wo awokose Jesu, eni ti o Fi ibinu re han nipa titan isoro kan. Nítorí náà, lo ìbínú rẹ láti wá ona abayo ti n tunkan se dípò tí yio Fi ba teniyan je. Ohun kan pàtàkì nípa irú ìbínú yìí ni pé a kì í Fi n dojuko awon èniyàn ṣùgbon a Fi n dojuko oun ti a se Lona aito. Nínú ẹsẹ karun nínú Bíbélì kíkà a sọ pé: “Nígbà tí ó ti wò won yíká pelú ibinu, tí inú rẹ̀ bàje, nitori líle ọkàn-àyà wọn, . . ..” Inú Jésù kò bàje sí àwọn èèyàn náà bí kò ṣe ohun tí won ṣe. A gbudo mu okàn wa dagba gege bi onigbagbo lati ma Dari ibínu wa si awon ènìyàn bikose SI oun ti o fa iwa ibaje won. A ko gbudo binu ti awon ènìyàn ko ba teti si awon aba wa. Ṣùgbon a gbodọ̀ bínú nígbà tí a bá ń Fi aiṣododo re awon ẹlòmíìran je. A le binu nigbati a ba pa elomiran lara. A le re ibínu wa sile nigba ti a ko ba bori à tí a bá kùnà láti bori itakuroso Tabi nibgba ti won ba se wa Tabi ti a ko wa sile. Ibinu imọtara-ẹni kii ṣe iranlọwọ fun ẹnikẹni.
BIBELI KIKA: Máàkù 3:1-5
ADURA: Baba ni orukọ Jesu jẹ ki Ẹmi rẹ kọ mi lati lo ibinu ni ọna ti o n tu nnkan se ti o si se itẹwọgba niwaju rẹ. Amin