THE SEED
“All the commandments which I command thee this day shall ye observe to do, that ye may live, …” Deuteronomy 8:1(KJV).
The plan and settings of the Lord are for us to go into the world and multiply in every area of our lives. Unfortunately, while men slept, his enemy came and sowed tares among the wheat thereby giving room to drought in the life of man and making us shift away from the original plan of God to suffer but our God is a man of war that can do all things, by the time He arises on our behalf, our enemies are rendered useless as we start to enjoy peace and blessings in all areas of our lives again. During Prophet Elisha, he was in a city and the people told him the situation of the city was good but the water was not and the ground was barren. But God through Elisha healed the water through a bowl of salt. God is the only one who can change a bad situation to a pleasant one by removing the famine and replacing it with abundance. The same happened with King Ahab and the Israelites in the time of Prophet Elijah, there was a drought in the land, no rain but by the time God showcased His Mighty Power over all Baal worshipers, through Elijah again rain fell, drought and famine vanished, only God can do what no man can do, all the drought and famine situation you see today in your life will disappear when the Lord have His way. You will have a change of story and you will sing a new song with Abundance of everything on all sides.
BIBLE READINGS: 1 King 18: 41 – 45
PRAYER: Oh God my Father, I pray that every area of my life shall receive abundance in Jesus’ Mighty Name. Amen
OPIN ÌYÀN NÁÀ
IRUGBIN NAA
“Gbogbo òfin tí mo palaṣẹ fún ọ li òní ní ki ẹyin ma kíyèsi lati ṣe, ki ẹyin ki o le ye, … Deuteronomi 8:1
Ètò àti ìlàkalẹ̀ Olúwa fún wa ni láti lọ sínú ayé kí a sì pọ̀ síi yíká nínú ohun gbogbo ni ìgbésí ayé wa. O ṣe ni laanu, pé nigbati awọn ènìyàn sùn, ọtá rẹ wá o si gbìn èpo sí ãrin awọn alikama nipa fifi aye silẹ fún ọ̀da ninú aye eniyan ati mímú wà sún kuro lọdọ ètò akọkọ ti Ọlọrun; lati jìnà sí jiya; ṣugbọn ologun ni Ọlọrun wa ti o le ṣe ohun gbogbo. Ni kete ti o ba dide nitori wa, a o sọ ọtá wa di asan ati ẹni yẹpẹrẹ, a o si bẹrẹ si gbadun alaafia ati ibukun ni gbogbo awọn ọnà aye wa lẹẹkansi. Nígbà wòlíì Èlíṣà, ó wà ní ìlú kan, àwọn èniyàn náà sì sọ fún un pé itẹ̀do ìlú náà dára ṣùgbọ́n omi náà kò rí bẹ́ẹ̀, ilẹ̀ sì ti ṣa. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti ipasẹ̀ Èlíṣà wo omi náà sán nípa iyọ nínú àwokòtò kan. Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè yí ipò búburú padà sí èyí tó dára, nípa mímú ìyàn náà kúrò, tó sì fi ọ̀pọ̀ yanturu rọ́pò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣẹlẹ̀ sí Ọba Ahabu àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé wòlíì Èlíjà, ọ̀dá wà ní ilẹ̀ náà, kò sí òjò ṣùgbọ́n nígbà tí Ọlọ́run fi agbára ńlá rẹ̀ hàn lórí gbogbo àwọn wòlíì Báálì, nípasẹ̀ Èlíjà òjò tún rọ̀, ọ̀dá àti ìyàn pòórá. Ọlọrun nikan lo le ṣe ohun ti eniyan ko le ṣe, gbogbo ipo ọ̀da ati ìyàn ohun rere ti o ri loni ninu aye rẹ yio parẹ nigbati Oluwa ba fi ara Rẹ hàn nínú ayé rẹ. Itan ayé rẹ yíò yipada ati pe iwọ yio kọ orin tuntun pẹlu ọpọlọpọ ohun gbogbo dáradara ni àyíká rẹ.
BIBELI KIKA: 1 Ọba 18:41-45
ADURA: Ọlọrun baba mi, mo gbadura pe gbogbo ayíká aye mi, yio ri ọpọlọpọ ohun rere gba lórúkọ Jesu alagbara Amin.