THE POWER IN THE NAME OF JESUS

THE POWER IN THE NAME OF JESUS

THE SEED

“The name of the Lord is a strong tower; The righteous run to it and are safe.” Proverbs 18:10 NKJV

In a world filled with uncertainties, fear and challenges, there is one constant source of refuge and strength-the name of Jesus. Proverb 18:10 beautifully captures the essence of the safety and security found in His name. Imagine Jesus name as a fortified tower, a place of unshakable strength and protection. Just as the ancient cities had tall and fortified walls to shield them from enemies, the name of Jesus serves as our invincible defense. It’s a name that demons tremble at and sicknesses bow down to. When we speak His name with faith, we invoke the power of heaven into our situations. When trouble surrounds us and we feel overwhelmed, we have the privilege of running to the name of Jesus. It’s not a sign of weakness, but of wisdom to seek refuge in the name of Jesus. Whether we face physical illness or spiritual battles, His name remains our sure place of refuge. As you go about your day, remember the authority and power vested in the name of Jesus. Speak His name over your circumstances with confidence, knowing that, in His name every knee must bow and every stronghold must crumble. Let His name be your first response in times of trouble and your constant declaration of victory.

BIBLE READING: Philippians 2:5-11

PRAYER: Lord, bestow on me the spirit to constantly use your name in our daily life and let it work wonders for me. Amen

 

 

ÀGBÀRÁ TO WÀ NÍNÚ ORÚKỌ JÉSÙ.

IRUGBIN NAA

“Orukọ Oluwa ilé ìṣọ agbára ní; olódodo sá wọ inú rẹ̀ o sí ye”. Owe 18:10

Nínú aye kan ti o kún fun awọn ai daniloju, ìbẹ̀rù ati awọn ìlàkọjá ti o ba ni lẹ́rú, orisun aabo ati agbara igbagbogbo wa nínú orukọ Jésù. Owe 18: 10 fi àpèjúwe tí o dára tọ́ka sí pataki ailewu ati aabo ti a ri ninu orukọ Rẹ. F’oju inu wo orukọ Jesu bi ilé olódi ti o lagbara, ibi tí agbára àti ààbò tí kò lè mì wa. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlú ńlá ìgbàanì ti o ní ògiri gíga àti olódi láti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, orúkọ Jésù nṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ààbò wa, èyí tí a kò lè fi oju ri. Ó jẹ́ orúkọ tí àwọn ẹ̀mí èṣù ń wárìrì, tí àwọn àrùn sì ń tẹrí ba fún. Nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, èyí máa nmu wa pe agbára ọ̀run sọkalẹ sínú àwọn ipò ìdààmú ti a bá wa. Nígbà tí wàhálà bá yí wa ká, tí o sì rẹ̀ wá, a ni áǹfààní láti sá lọ sínú orúkọ Jésù. Kii ṣe ami ojo bikoṣe ọgbọn lati wa aabo lábẹ́ orukọ Jesu. Yálà a ń ṣàìsàn nípa tara tàbí a dojú kọ ìjà ti ẹ̀mí, orúkọ rẹ̀ ṣì jẹ́ ibi ìsádi wa tó dájú. Gẹgẹ bi , iwọ ti nlọ nipa ọjọ rẹ, ranti aṣẹ ati agbara ti a fi fun orukọ Jesu, Pe orukọ rẹ lori awọn àyídáyidà rẹ pẹlu Igbẹkẹle, mọ pe, ni orukọ Rẹ ni gbogbo ẽkun gbọdọ tẹriba ati gbogbo agbara kagbara gbọdọ wolẹ. Jẹ ki orukọ Rẹ ki o jẹ́ idahun akọkọ rẹ ti wahala ba yọ ju, ati ìpolongo rẹ nigbagbogbo nínú Iṣẹgun.

BIBELI KIKA: Filippi 2 : 5 – 11.

ADURA: Oluwa fun mi ni ẹmi lati máà lo orukọ Rẹ nigbagbogbo ni igbesi aye mi ojoojumọ, si jẹ́ ki o ṣiṣẹ́ iyanu fun mi. Amin.

Leave a comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *