THE SEED
”Watch therefore, for you know neither the day nor the hour in which the Son of Man is coming.“ Matthew 25:13 NKJV
The Lord, in His parables of the ten virgins, tells us that the time of His coming is unknown to anyone: meaning it could be any time! I mean it could be today!! People of God can become unprepared because they choose to live carefree lifestyles, just like in the days of Noah. He warned the people about the flood but they did not listen. A true Christian needs to make a wise choice. Satan didn’t want people to serve and work for God. The devil comes to kill, steal and destroy. No matter the circumstances you must have a great desire to do the work of God, be steadfast and uphold Him tightly. Because the devil lies patiently ahead awaiting in ambush looking for who to devour, As children of God, we need to make ourselves ready at all times, living a righteous and holy life. Five among the ten virgins served and did the will of the bridegroom. This is what the Lord expects from those awaiting His coming. We must keep our lamps burning, and keep living according to God’s word. If we strive to do God’s will He will give us the grace to overcome temptations and to keep the fire burning in us. Those who are unprepared are likely to fall into the trap of the devil. The hook, line and bait are the traps the devil set for the unprepared ones. Let us be careful not to fall for it.
BIBLE READINGS: Matthew 24:36-39
PRAYER: O Lord give me the strength to be fully prepared for your second coming in Jesus’ Name. Amen.
ÀWỌN ALAIMURASILẸ
IRUGBIN NAA
“Nitorinaa ẹ máà ṣọ́na, bí ẹ̀yìn kó tí mọ ọjọ, tàbi wákàtí tí Ọmọ-ènìyàn yió de” Matteu 25:13
Oluwa ninu owe Rẹ̀ ti awọn wundia mẹwa, sọ fun wa pe àsìkò wiwa Òun ko hàn fun ẹnikẹni: èyí túmọ̀ si pe o le jẹ igbakugba! O lé jẹ́ lónì!! Àwọn ènìyàn Ọlọ́run le wa ni aigbaradi nitori wọ́n yan lati gbe igbesi-aye aibikita, gẹgẹbi awọn ọjọ ti Noa. Ó si kìlọ fun awọn enia nipa awọn ìkún omi ṣùgbọ́n wọ́n ko fetísílẹ. Kristiani otitọ nílò lati yàn ohùn ti o tọ. Eṣu kò fẹ ki awọn eniyan sin, tàbí ṣiṣẹ fun Ọlọrun. Eṣu wá làti pa, làti jalè ati láti parun. Bi o ti wù kí ó rí, o gbọdọ ní ìpinnu ńlá lati ṣé iṣẹ́ Ọlọ́run, duro ki o si di i mu ṣinṣin. Nítorí eṣu fi pẹlẹpẹlẹ duro ni bùba, o n wa ẹni ti yíò pa jẹ. Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ọlọ́run, a ní láti múra sílẹ̀ ní gbogbo ìgbà, ní gbígbé ìgbé ayé mímọ́ àti òdòdó. Márùn-ún lára àwọn wúńdíá mẹ́wàá náà sìn, wọ́n sì ṣe ìfẹ́ ọkọ ìyàwó. Eyi ni ohun ti Oluwa nreti lati ọdọ awọn ti nduro de wiwa Rẹ. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn fìtílà wa máa jó, ká sì máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ti a ba ngbiyanju lati ṣe ifẹ Ọlọrun Oun yíò fun wa ni oore-ọfẹ lati bori awọn idanwo ati lati jẹ ki ina njo ninu wa. Ó ṣeé ṣe kí àwọn tí kò múra tán ṣubú sínú ìdẹkùn eṣu. Awọn ìkọ, ila ati ìdẹ jẹ awọn ìdẹkùn ti eṣu ṣeto fun awọn ti ko mura silẹ. Ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra kí á má bàa ṣubú sínú rẹ̀.
BIBELI KIKA: Mátíù 24:36-39
ADURA: Oluwa fun mi ni agbara lati mura ni kíkún, fun ìpadàbọ̀ ẹlẹ́kejì Rẹ̀ ni orukọ Jesu. Amin