THINK BIG

THE SEED
“Above all else, guard your heart, for everything you do flows from it. Keep your mouth free of perversity, keep corrupt talk far from your lips.” (Proverbs 4 : 23 – 24)

 

Brothers and sisters in the Lord time has come that we need to change the level of our operations in the realm of the spirit. The above scripture encourages us to guard our hearts, for out of it flows life and our mouth is the authority of power. We need to think big because out of the abundance of the heart the mouth speaketh (Matthew 12:34) and we should not also forget that as you have said in my ear, so will I do to you (Numbers 14:28). What are you saying to your life and that of your and family? if you can think big of where God is taking you, not looking at your present condition, and with faith you can speak it out into your life and that of your children and family, I can assure you, God will take you there.

BIBLE READING: Numbers 23 : 19

PRAYER: Oh Lord, thank you because my tomorrow and that of my family is great in you.

                                                             NÍ ÈRÒ TÓ GA

IRUGBIN NAA

“Jù gbogbo ohun ìpamọ, pá àyà rẹ mọ nitori pé lati inu rẹ wá ní orísun ìyè. Mu arekereke kuro lọdọ rẹ̀, àti ètè ẹtan jìnà réré kúrò lọdọ rẹ̀.” Owe 4:23-24

 

Arakunrin ati arabinrin ninu Oluwa, àsìkò ti dé lati yí ipele ìhùwà sí wa, padà nínú ẹ̀mi. Ẹkọ tí a kọkọ ka gbà wá níyànjú láti ṣe atọkun fún ọkàn wa  nitori pe ninu rẹ ni orisun ìyè tí nṣan; ati ẹnu wa sí ni  agbara àṣẹ. A nilo lati ni ero nla, nitori lati inu ọ̀pọlọpọ èrò inú ọkàn li ẹnu nsọrọ Matteu 12:34 ati pe a ko gbọdọ gbagbe pẹlu pe ohun ti ẹ ba sọ li etí mí ni èmi yio ṣe, Numeri 14:28. Kíni èrò rẹ fún igbesi ayé rẹ, fún igbesi aye awọn ọmọ ati ẹbi rẹ? Ti o ba le ní èrò nla, fún ibiti Ọ́lọrun rẹ n mu ọ lọ, la i wo ipo rẹ lọwọlọwọ, ati pẹlu igbagbọ o le sọ jade sinu igbesi aye rẹ ati ti awọn ọmọ ati idile rẹ, Mo le fí da ọ loju pe, Ọlọrun yíó mu ọ de ibẹ.

BIBELI KIKA: Númérì 23:19

ADURA: Oluwa mo dupẹ́ lọwọ Rẹ, nitoripe ọ̀la mi ati ti idile mi yíó wà ni ipo ti o ga ninu Rẹ.

Leave a comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *