TRANSFORMING YOUR LIFE
THE SEED
“Do not be conformed to this world, but be transformed by the renewal of your mind, so that you may prove what is the good, acceptable, and perfect will of God.” — Romans 12:2 (NIV)
God has a purpose for each of us, but to walk in His perfect plan, we must undergo transformation. This transformation begins in the mind-renewing our thoughts, attitudes, and perspectives through God’s Word.
We were not created to live ordinary, stagnant lives. God desires to elevate us, to take us to new levels of growth and blessing. The disciples experienced transformation after spending 40 days with Jesus following His resurrection. The woman with the issue of blood experienced transformation the moment she touched Jesus’ garment. Regardless of where we are in life, we all desire to be transformed for the better. But transformation does not happen by conforming to the world’s standards. Instead, it happens when we embrace God’s truth, align ourselves with His will, and continually seek Him.God has placed within us everything we need to live a victorious life. It is time to draw it out and walk in His divine purpose.
BIBLE READING: Romans 12:2-4
PRAYER: Lord Jesus, transform my life for the better. Renew my mind and align my heart with Your perfect will. Amen.
YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ RE PADA
IRUGBIN NAA
Ẹ má ṣe ṣe àfarawé ayé yìí, ṣùgbọ́n ẹ yí padà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí ohun tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé, tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. Róòmù 12:2 (NIV).
Ọlọ́run ní ète kan fún olúkúlùkù wa, àmọ́ ká tó lè máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ètò pípé tó ṣe, a gbọ́dọ̀ yí padà. Ìyípadà yìí bẹ̀rẹ̀ nípa yíyí èrò inú wa, ìṣesí wa, àti ojú ìwòye wa padà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọlọ́run ò dá wa pé ká kàn máa gbé ìgbésí ayé lásán. Ọlọ́run fẹ́ gbé wa ga, ó fẹ́ mú wa dàgbà, ó sì fẹ́ bù kún wa.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà rí ìyípadà yìí lẹ́yìn tí wọ́n lo ogójì ọjọ́ pẹ̀lú Jésù lẹ́yìn àjíǹde Rẹ̀. Obìnrin tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ náà yí padà gbàrà tó fọwọ́ kan ẹ̀wù Jésù.
Láìka ipò yòówù ká wà nínú ayé, gbogbo wa la fẹ́ kí Ọlọ́run yí wa pa dà sí rere. Àmọ́, kì í ṣe nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà ayé ni ìyípadà fi ń wáyé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó
máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí a bá gba òtítọ́ Ọlọ́run, tí a bá mú ara wa bá ìfẹ́ Rẹ̀ mu, tí a sì ń wá Rẹ̀ nígbà gbogbo. Ọlọ́run ti fi gbogbo ohun tí a nílò sínú wa láti gbé ìgbé ayé aṣẹ́gun. Àkókò nìyí láti mú un jáde, ká sì máa rìn nínú ète atokewa Rẹ̀.
BIBELI KIKA: Róòmù 12:2-4.
ADURA: Jésù Olúwa, yí ìgbésí ayé mi padà sí rere. Mú kí ọkàn mi wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ tí ó pé. Àmín.