PROCLAIMING GOD’S GOODNESS
THE SEED
“And he departed and began to proclaim in Decapolis all that Jesus had done for him, and all marvelled.” Mark 5:20 NKJV
When God does something marvellous in our lives, the best response from us is to give testimony by sharing it in church, with our friends, families too. When Jesus healed the madman of Gadarenes, he wanted to follow Jesus, but He told him to proclaim the marvellous miracle he had received. He went around spreading the good news and how he got healed, and people marvelled and believed God more, that is the power of testimonies. These days many brethren are too shy and timid to share their testimonies about how God healed them from sickness, delivered them from battles, accidents to mention a few. They keep hiding their testimonies and are scared to tell people about the goodness of God in their lives, God is not pleased with such people, as it amounts to ungratefulness. Proclaiming God’s goodness helps to strengthen the faith of other believers. When you share your testimonies, someone too might be going through that same situation that God delivered you from, they then tap into your testimony and develop a strong believe that God can do theirs since He did it for you. God desires us to share our testimonies within our family office, school, church, and other gatherings, to let them know God can do all things.
BIBLE READING: Mark 5:18-20
PRAYER: Oh Lord, help me to proclaim your good works in my life without any shame. Amen
PÍ POLONGO IRE OLUWA.
IRUGBIN NAA
“O sí padà lọ, o bẹ̀rẹ̀ sí ima rohìn ni Dekapoli, ohun ńlá tí Jésù ṣe fun ún: ẹnu sí ya gbogbo eniyan.” Marku 5:20.
Nígbàtí Ọlọ́run bá ṣe ohun àgbàyanu nínú ìgbésí ayé wa, àfihàn rẹ̀ tó dára jù lọ láti ọ̀dọ̀ wa ni láti jẹ́rìí, nípa sí sọ dí mí mọ nínú ìjọ, pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa, àwọn ẹbí àti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń la irú ipò bẹ́ẹ̀ kọjá pẹ̀lú. Nígbà tí Jésù wo aṣiwèrè ará Gádára sàn, ó fẹ́ tẹ̀ lé Jésù, ṣùgbọ́n ó sọ fún un pé kí ó kéde iṣẹ́ ìyanu àgbàyanu tí òun ti rí gbà. Ó lọ yí ká, láti kéde ìhín réré naa kálẹ ̀ àti bí a ti ṣe mú ú lára dá, ẹnu sì yà àwọn ènìyàn, wọ́n sì gba Ọlọ́run gbọ́ sí i, èyí ni agbára ẹ̀ri. Lóde oni ọ̀pọ̀ àwọn ara nínú Olúwa ni o máà ń tijú láti sọ ẹ̀rí nípa bí Oluwa ṣé wo wọn san kúrò nínú àìsàn, nínú ogun tí ó dojú kọ wọ́n, ati gbígbà wọ́n lọ́wọ́ ìjàm̀bá ọkọ̀ ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n ń fi ẹ̀rí wọn pa mọ́, wọ́n sì máa ń bẹ̀rù láti máa sọ nípa oore Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn nínú ìgbésí ayé wọn. Inú Ọlọ́run kò dùn sí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ àlaìmoore. Kíkéde oore Ọlọ́run máa ń jẹ́ ki áwọn ènìyàn túbọ̀ ní ìgbàgbọ́ ti o fi idi múlẹ̀. Nígbàtí o bá sọ àwọn ẹri rẹ, ẹnikan le wa ni irú ipo kanna; lẹhin ijẹri rẹ̀, wọ́n yió gbagbọ pe Ọlọrun tun le ṣe ti wọn, níwọ̀n ìgbà ti o ti ṣe fun ọ. Ọlọrun fẹ ki a ṣé ijẹ́ri wa, bẹ̀rẹ̀ lati ile wa si ibi ìṣẹ́, Ile-iwe, Ile-ijọsin ati awọn apejọ lati jẹ ki wọn mọ pe Ọlọrun le ṣe ohun gbogbo.
BIBELI KIKA: MARKU 5:18:20
ADURA: Oluwa, ràn mí lọwọ lati kéde iṣẹ́ Rẹ nínú aye mí lai sí ìtìjú. Amin.