GOD CAN DO ALL THINGS
THE SEED
“And he said, The things which are impossible with men are possible with God.” — Luke 18:27 KJV
God’s power has no limit, while man’s strength is full of boundaries. The Scriptures abound with miracles that defy logic: Abraham and Sarah conceived in old age, ravens fed Elijah, an axe head floated, and a widow’s oil never ran dry. These are not mere stories—they are testimonies of divine power at work. Human ability ends quickly, but God’s ability knows no end. He specializes in turning impossibilities into testimonies. To trust Him is to hand over your limited strength and receive His boundless power. Faith is the bridge between man’s weakness and God’s omnipotence. When we surrender completely, He steps in with wisdom, power, and breakthroughs beyond imagination. What situation have you considered impossible that you need to place in God’s hands?
BIBLE READINGS: Luke 18:27–30
PRAYER: Lord, nothing is too hard for You. I trust You to do the impossible in my life. Amen.
ỌLỌRUN LE ṢE OHUN GBOGBO
IRUGBIN NAA
“O si wipe, Ohun ti o ṣoro lọdọ enia, kò ṣoro lọdọ Ọlọrun.” Luku 18:27 YBCV
Agbara Ọlọrun kò ní ààlà, ṣùgbọ́n agbára ènìyàn ní òpin. Ìwé Mímọ́ kún fún àwọn ìyanu tí ó kọjá èrò ọkàn ènìyàn: Ábràhámù àti Sárà bí ọmọ ní ọjọ ogbo, ẹyẹ iwo gbe onjẹ wa fun Èlísà, ori akeke lefo loju omi, bẹ ẹ na ni kolobo ororo obirin opo kan ko gbẹ. Èyí kì í ṣe àròsọ lasán — wọ́n jẹ́ ẹ̀rí agbára iṣẹ iyanu Ọlọrun. Agbára ènìyàn lópin, ṣùgbọ́n agbára Ọlọrun kò ní òpin rárá. Ó mọ bí a ṣe ń mu ohun tí kò ṣeé ṣe wa sí ìtẹ́ríba, ki o si di ṣeṣe. Láti gbẹ́kẹ̀lé E jasi pe ki a jọwọ okun wa ti ko to nkan fun Un, kí a sì gba agbára àìnípẹ̀kun Rẹ̀. Ìgbàgbọ́ jẹ afara tó so àìlera ènìyàn pọ̀ mọ́ agbára Ọlọrun. Nígbà tá a bá fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ fún Un, Ọlọrun á wọlé pẹ̀lú ọgbọ́n, agbára, àti ìgbàlà tí ó kọjá ìròyìn ọkàn ènìyàn.
Ìpò wo ni o wa ti o ro pé kò ṣeé ṣe, tí o sì nílò láti fi sí ọwọ́ Ọlọrun lónìí?
BIBELI KIKA: Luku 18:27–30
ADURA: Oluwa, kò sí ohun tí ó ṣòro fún Ọ. Mo gbẹ́kẹ̀lé Ọ pé Ìwọ yóò ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe nínú ayé mi. Àmín