PEACE ON GUARD

PEACE ON GUARD

THE SEED

“And the peace of God, which transcends all understanding, will guard your hearts and your minds in Christ Jesus.” — Philippians 4:7 (NIV)

Like a guardian at the gate, God’s peace stands watch over our inner life. We cannot manufacture this peace; it is bestowed by God and surpasses understanding. When welcomed, it filters what enters our thoughts and settles what storms our emotions. Jesus once spoke to a raging sea, “Peace, be still,” and the wind obeyed (Mark 4:39). He can do the same within us. Guard your heart by guarding inputs—your thoughts, conversations, and influences and by drawing near in stillness and prayer. Let His peace take its post. With Christ’s peace on duty, you will not be easily shaken you’ll think clearly, choose wisely, and rest securely.

Reflection: When God’s peace stands guard, fear loses access.

BIBLE READING: Mark 4:35–41

PRAYER: Lord, be the Guardian of my heart. Let Your peace keep my mind and emotions steady in every storm. Amen.

 

ALAFIA TI NPA NI MO

IRUGBIN NAA:

Ati alafia Ọlọrun, ti o jù ìmọran gbogbo lọ, yio ṣọ ọkàn ati ero nyin ninu Kristi Jesu. Filipi 4:7

Gege bi olusogba ti nbe ni enu ibode, alafia Olorun duro, O nso emi wa. A ko le seda alafia naa, Olorun ni nfi fun ni, o si maa ju oye eniyan lo. Nigbati a ba faye gba a, yio maa bojuto awon ero okan wa ati ohun ti n da okan wa lamu. Jesu ba riru omi okun wi. “Dake je” iji si gboran (Marku 4:39). O le se bee gege ninu wa. Pa okan re mo nipa bibojuto awon ohun ti nwo ibe–ero re, oro re, awon ore re – ati sisunmo Olorun nipa idakeje ati adura. Je ki alafia Re ki o joba. Bi alafia Kristi ba joba, won ki yoo le mi o – iwo yoo maa ronu daradara, yan pelu ogbon, iwo yoo si sinmi ni ifokanbale.

ERO: Nigbati alafia Olorun ba pa o mo, iberu yio salo.

BIBELI KIKA: Marku 4:35-41

ADURA: Oluwa, je Oluso okan mi. Je ki alafia Re pa okan mi mo, ki o si mu mi duro ninu gbogbo iji. Amin

 

Leave a comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *