THE SEED
And they overcame him by the blood of the Lamb. Revelation 12:11
Your ability to overcome obstacles has nothing to do with the environment you are in. Your level of commitment is the determining factor. Every person has a situation. What you choose to do in certain circumstances is crucial. You will encounter issues on a daily basis as you live out your Christian life. To succeed in his Christian life, every Christian must overcome a challenge. The devil and his agents of darkness can be easily defeated with the blood of Jesus Christ. The devil and his agents of darkness can be easily defeated with the blood of Jesus Christ. The blood of Jesus was used by Archangel Michael and his angels to defeat the devil and his agents of darkness even in heaven. As Christians, we must never cease using the blood of Jesus because whenever we do, they are rendered helpless in our presence. The word of our testimony, which is another tool at our disposal, should not be taken lightly. When our Father or our Lord Jesus Christ does anything for us, no matter how minor or significant, we must not be silent about it or take it for granted. Our Father and our Lord Jesus Christ want to hear our testimony. Jesus Christ continues to perform miracles for us so that we can honour Him as we witness more and more. Our testimonials often make the enemy feel ashamed and helpless by exposing their deeds.
PRAYER
O Lord, let not voice of testimonies be silenced, give me cause to proclaim your greatness.
BIBLE READINGS: Revelation 12:8-12
AWON ASEGUN
IRUGBIN NAA
Wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀ nípa ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. Ìfihàn 12:11
Aṣẹ́gun túmọ̀ sí pe ohun kan wà ti a n doju ko, ti a ni ìpèníjà lori re, àti ti a ni lati bori. Agbara rẹ lati bori awọn idiwọ ko ni fi ṣe pẹlu agbegbe ti o wa, Ifarajin re ni o se akajuwe. Olukuluku eniyan wa ni ipo kan tabi omiran. Ohun ti o ba yan lati ṣe ni awọn ipo kan ṣe pataki. Iwọ yoo ri awon ipanija lojoojumọ bi o ṣe n gbe igbesi aye Onigbagbọ rẹ. Lati se aseyori ninu Krisiti, gbogbo Kristieni ni lati bori awon ipenija., Eṣu ati awọn omo ogun rẹ ni a ṣẹgun nipa ẹjẹ Jesu Kristi. Eṣu ati awọn omo ogun okunkun ni a le ṣẹgun pẹlu ẹjẹ Jesu Kristi. Ẹ̀jẹ̀ Jésù ni Máíkẹ́lì Olú-áńgẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti ṣẹ́gun Esu àti àwọn omo ogun òkùnkùn rẹ̀ àní ní ọ̀run. Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a kò gbọ́dọ̀ ṣíwọ́ lílo ẹ̀jẹ̀ Jésù láé nítorí pé nígbàkigbà tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a maa sọ awọ́n okunkun yi di aláìlágbára níwájú wa. Ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wa, tí ó jẹ́ irinṣẹ́ mìíràn tí o wà lọ́wọ́ wa, kò yẹ kí a fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú. Nígbà tí Bàbá wa tàbí Olúwa wa Jésù Kristi bá ṣe ohunkóhun fún wa, láìka bí ó ti wù kí ó kéré tó tàbí tó ṣe pàtàkì tó, a kò gbọ́dọ̀ dákẹ́ nípa rẹ̀ tàbí kí a ma kaa si. Bàbá wa àti Jésù Kírísítì Olúwa wa fẹ́ gbọ́ ẹ̀rí wa. Jésù Kristi ń te siwaju láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu fún wa kí a baà lè bu ọlá fún un bí a ṣe ń jẹ́rìí sí i. Awọn ẹri wa nigbagbogbo jẹ ki awọn ọta ni itiju ati je ailagbara pelu nipa ṣiṣafihan awọn iṣe wọn.
ADURA
Oluwa, ma je ki ohun ijeri dake, fun mi ni agbara lati kede titobi Re. Amin.
BIBELI KIKA: Ìfihan 12:8-12