THE SEED
“For the eyes of the Lord are over the righteous, and His ears are open unto their prayers: but the face of the Lord is against them that do evil.” 1 Peter 3 : 12 KJV
The Immortal God our Father is invisible and the only way to communicate with Him is through prayer, then through the scriptures, we are taught that God will always hear our prayers and will answer them if we address Him with faith and real intent. In our hearts we will feel the confirmation that He does hear us, a feeling of peace and calm. We can also feel that everything will be fine when we follow the Father’s will. You do not need any special style or try to copy anybody to request from your Father, but talk to God as your Father, your friend and a Judge, He is with all ears to answer you at all times. God said if ye then being evil, know how to give good gifts unto your children, how much more shall your Father which is in Heaven give good things to them that ask Him. Furthermore He said which among you will the son ask him for bread and he will give him stone, or ask for fish and he will give serpent or ask for egg he will give scorpion, so brethren be bold to go before your Father and Creator ask from Him what ever you want, He listens though you can ask and do not receive, if you ask amiss, that you may spend it on your pleasure.
BIBLE READING: Matthew 7 : 6 – 11
PRAYER: The Confidence and Faith we need to request from our Father in Heaven we will be given in Jesus Name. Amen.
ỌLỌRUN MÁA NGBỌ
IRUGBIN NAA
“Nitorí ojú Olúwa mbẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ sí ṣí sì ẹ̀bẹ̀ wọn: ṣugbọn ojú Olúwa nwo awọn ti ńṣe búburú.” 1 Peter 3:12
Ọlọ́run àìkú, baba wa ti a kò lè rí, àti pé ọ̀nà kan ṣoṣo láti bá a sọ̀rọ̀ ni nípasẹ̀ àdúrà, latí ipasẹ̀ àwọn ìwé mímọ́, a kọ́ wa pé Ọlọ́run yió máa gbọ́ àdúrà wa nígbà gbogbo, yió sì dáhùn tí a bá bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti iro tí o jinlẹ̀. Nínú ọkàn wa, a ní ìmọ̀lára ìmúdájú pé Ó ń gbọ́ wa, ìmọ̀lára àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkan. A tun le lero wipe ohun gbogbo yió dara nigba ti a ba tẹle ifẹ baba. Iwọ ko nilo lati kọ́ aṣa eyikeyi lati ọ̀dọ ẹnikẹni lati beere lọwọ baba rẹ, rárá ṣugbọn ba Ọlọrun sọ̀rọ̀ bi baba rẹ, ọrẹ rẹ ati onidajọ. Ó wà pẹ̀lú gbogbo etí láti dá ọ lóhùn nígbà gbogbo. Ọlọ́run sọ pé bí ẹ̀yin tí jẹ́ ẹni ibi, ẹ mọ bí a ti ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run kì yíò fi ohun rere fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Pẹlupẹlu O sọ pe tani ninu yin ti ọmọ rẹ beere akara lọwọ rẹ tí yíò fun u ni okuta, tabi beere ẹja ti yíó fun ní ejo tabi beere ẹyin ti yoo fun ni akẽkẽ; nitori naa ará, ni igboya lati lọ siwaju Baba ati Ẹlẹda rẹ, beere lọwọ Rẹ ohunkohun ti o ba fẹ. O ngbọ, bi o tilẹ beere ti o kò sì rí gbà, ti o ṣi béèrè lati lo fún ifẹkufẹ.
BIBELI KIKA: Matteu 7:6-11
ADURA: Ìgboyà àti ìgbàgbọ tí a nilo lati béèrè lọwọ Bàbá wa ti nbẹ́ l’ọ́run ní a o fi fún wa ní orúkọ Jésù Àmín.