THE SEED
“For our light affliction, which is but for a moment, worketh for us a far more exceeding and eternal weight of glory;” 2 Corinthians 4:17
Most often in life, the end of the road is but a bend In the road. When we feel we have nothing left to give and we are sure that the song has ended; When our day seems over and the shadows fall and the darkness of night has descended; Where do we go to find strength to keep on trying; Where can we find a hand to dry the tears we are crying; There’s but one place to go and that is to God. Remember it is not about having faith in yourself, it is about having faith in God. It is not about losing hope; it is about being patient and hopeful in God. It is about persistence, which activates the mercy of God to bring His comforting Spirit upon you. It is about negotiating both spiritual and physical bend to get the crown that will last forever, and that should be our goal in life as Christians. Let’s rest and relax and grow stronger, Let go and let God share your load; your work is not finished or ended,you have just come to a “bend in the road.”
BIBLE READING: 2 Corinthians 4
PRAYER: Heavenly Father order my foot step in this journey of life, carry my burden that I may find rest in you
IBI WIWO NI ONA NAA
IRUGBIN NAA
“Nitori iponju wa ti o fere, ti ise fun iseju kan , o n sise ogo ainioekun ti o po rekoja fun wa.” II Korinti 4:17
Ni opo igba laye, ibi ti o wo ni oju ona kii se opin ona. Nigba ti a ba n ro wipe ko tun si ohun kan ti a le se, ti o da wa loju wipe orin ti pari, nigba ti o dabi eni pe ojo wa ti fe pin, ti ojiji subu, ti okunkun si su bole; nibo ni a le lo lati ri okun lati tesiwaju, nibo ni a ti le ri owo ti yio nu omije wa nu? Ibi kan soso ni o wa ti a le lo, odo Olorun si ni. Ranti wipe kii se nipa nini igbagbo ninu ara re bikose ki o ni igbagbo ninu Olorun. Kii se nipa siso ireti nu sugbon ki a ni suuru ati ireti ninu Olorun. Ki a maa tesiwaju, eyi a maa mu ki aanu Olorun ki o mu emi mimo Olutunu wa sinu aye re. A ni lati gba ona ti o wo ni koja nipa ti ara ati nipa ti emi ki a baa le gba ade ti yio wa titi lae, eyi si ye ki o je ilepa wa gege bi onigbagbo. E je ki a sinmi, ki a fara bale, ki a si di alagbara. Fi gbogbo re sile fun Olorun ki o ba o gbe eru re, ise re kotii tan tabi pari, o ko n koja ni ona ti o wo ni.
BIBELI KIKA: II Korinti 4
ADURA: Baba mi orun, to isise mi ninu irin ajo aye yii, gbe ajaga mi, ki nle ni isinmi ninu re. Amin