BE EXCEPTIONALLY DILIGENT IN WHAT YOU DO
THE SEED
“Seest thou a man diligent in his business? he shall stand before kings; he shall not stand before mean men”. Proverbs 22:29 KJV.
Dear brethren, ask for the grace for an extra mile of hard work more than your friends are doing. That is what will make you extraordinary. When we serve with diligence and enthusiasm in those tasks we are called upon to take on, do you know we magnify and enlarge our calling? Learning is not attained by chance, it must be sought with passion and diligence. Diligence is the mother of good fortune that will produce a better you. Be Diligent and never let the charms of procrastination and excuses distract you from falling for mediocrity. Do you know that “Work is doing it? Discipline is doing it every day, while diligence is doing it well, every day” I pray that God will give you the power to carry out all your daily assignments diligently and well in Jesus name. When you love your work, you will be exceptionally Diligent in what you do and you will excel in delivering both quality and quantity. Determine that your hands will not be weak. Determine that your Diligence and Focus will increase.By the grace of God, your best days are still ahead and it is well with you in Jesus name.
BIBLE READING: Hebrews 6: 9-12
PRAYER: My Lord, uproot discouragement or depression from my life and lose fresh zeal. Father, clothe me with diligence and progress in Jesus name.
FI ARÁ RẸ HÀN NÍ ALAI ṢÉ IMẸLẸ NÍNÚ OHUN TI O BÁ ŃṢE
IRUGBIN NAA
“Ìwọ rí ènìyàn tí ó nfi àiṣèimẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ? on o dúró níwájú àwon ọba; on kí yíò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán. Òwe 22:29.
Ẹ̀yin ará, ẹ béèrè oore-ọ̀fẹ́ fún iṣẹ́ àṣekára ju bí àwọn ọ̀rẹ́ yín ṣe ńṣe lọ́wọ́lọ́wọ́, èyí yíò jẹ́ ÀGBÀYANU! Nígbàtí a bá sìn, pẹ̀lú àiṣè imẹ́lẹ́ àti ìtara nínú àwọn ojúṣe wọnnì, ti a pè wá láti ṣe; Ǹjẹ́ o mọ̀ pé a o gbé ìpè wa ga tí yó ó sì máa pọ̀ sí i? Ẹkọ ki ka kì i ṣé ohun tí a gbà lójijì, a ní láti wa a pẹlu àiṣè imẹ́lẹ́ ati itara. Àiṣè imẹ́lẹ́ ní ìyá fún àṣeyọrí réré, ti yió mú iṣẹ́ réré jade ni ara rẹ. Jẹ́ alàiṣè imẹ́lẹ́, ma ṣé jẹ́ kí ọfà ifi àkókò dá ọ̀la pẹ̀lú àwáwí tan ọ lati ṣubu bí aláìmọ́ kan. Ṣé o mọ̀ wipe “Ìṣe lo njẹ́ ṣíṣe ohun kàn? Ibawi ni ṣíṣe ohun kán lójoojúmọ́, Àiṣè imẹ́lẹ́ ni ṣíṣe ohun kán lójoojúmọ dáradára” Mo gbadura pe, ki Ọlọ́run fun yin ni agbara lati maa ṣe gbogbo ìṣe yìn ojoojumo dáradára ati làiṣè imẹ́lẹ́ ni orúkọ Jésù. Nigbati o ba nifẹ iṣẹ rẹ, iwọ yió jẹ Alaapọn ti o yatọ ninu ohun ti o nṣe, ati pe iwọ yió tayọ nínú àṣeyọrí nipa àgbè kalẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ àti ojúlówó! Pinnu pé ọwọ́ rẹ ki yió jẹ alailagbara! Pinnu pe àiṣè imẹ́lẹ́ ati àfojúsùn rẹ yió pọ si! Nipa oore-ọfẹ Ọlọrun, awọn ọjọ rẹ ti o dara julọ si n bọ, yio si dara fun ọ ni orukọ Jesu.
BIBELI KIKA: Heberu 6: 9-12.
ADURA: Oluwa mi, fa gbongbo irẹwẹsi tabi ibanujẹ tu kúrò nínú ayé mi, kí ó si tú itara títún silẹ fun mi. Baba, wọ mí ni aṣọ àiṣè imẹ́lẹ́ àti ìlọsíwájú ni orúkọ Jesu. Amin.