Focus On The End

THE SEED
“The end of a matter is better than its beginning….” Ecclesiastes 7:8a NIV

This scripture applies to every aspect of our lives, be it secular, professional, marital and spiritual. The gist is that there’s nothing wrong with starting little or poorly in life, but along the way you must have drive and aspirations for improvement. Maybe you’re in a new job or a new role at work and you feel that you don’t have enough experience, don’t be discouraged or intimidated, remind yourself that it’s the beginning. Invest time to learn from materials and people around, focus on how you will be the best at the end. Also in marriage, focus on the future success, put in effort, and don’t allow the lack of now to dictate the result. As a student, you might struggle in the beginning but make up your mind to be a star at the end of your school calendar. Most importantly, as a Christian, you can experience struggles at the beginning, caused by fleshly desires and life challenges. Be motivated by the words of Jesus “he that endure to the end shall be saved Mat 24:13.

PRAYER

Lord, please endow me with the enablement to have a successful end Jesus Name. Amen

BIBLE READINGS: Job 42:7-17

NI AFOJUSUN FÚN IGBA ÌKẸHÌN

IRUGBIN NAA

“Òpin nkan sàn ju ipilese rẹ lọ: àti onisuuru ọkàn jù ọlọkàn igberaga.” Oniwaasu 7:8a

Ẹkọ kíkà yi wá fún ohun gbogbo nínú ayé wa. Fún àpẹrẹ iṣẹ tí a nṣe, iṣẹ tí a yàn láàyò, igbeyawo ati ìmọ nínú èmi. Èyí jẹ ohun tí o dára, kò sí ohun tí o burú, ti a bá bẹrẹ pẹlú ohun
kékeré tabi a jẹ alaini nínú ayé: Sugbọn nínú ìrìn àjò yí a gbọdọ ní ọkàn àti ìpinu fún iserere. Yálà o wa ní ibí iṣẹ tuntun tàbí ipò kàn, ti o sí woyé pé o kò ní ìmọ ti o péye nínú iṣẹ náà;
ma ro ará rẹ pin tàbí fetí sí yeye ti awọn eniyan nfi ọ ṣe. Wa àyè láti ní ìmọ̀siwaju síi nipa ohun ti o fí nṣe iṣẹ náà lati ọdọ awọn eniyan layika rẹ. Dojú kọ bí o tí ṣe lè jẹ ẹnití o mọ iṣe náa ju ẹnikẹni lọ. Nínú ìgbéyàwó dojú kọ aseyori ọjọ iwájú, sa ipá, má sí ṣe gba fún àìní isisiyi, tọka sí bi òpin igbeyawo yíó ti rí. Gẹgẹ bí akẹkọ o le máa tiraka ni bẹrẹ, sugbọn ṣe ìpinnu nínú ará rẹ pé nikẹhin iwọ ni yíó tayọ ninu ile ẹkọ rẹ.Pataki julọ gẹgẹ bí Kristẹni o le ni awọn iṣoro kan ni bẹrẹ, ti o le wa lati ọdọ ifekufe ẹran ati ipenija nínú ayé; jékí ọrọ Jésù máa rú ọ soke wipe: “Enikeni ti o bá foriti dopin ní ao gbala” Matteu 24:13

ADÚRÀ

Olúwa jọwọ fún mi ni okun lati le ṣe àṣeyọrí dopin ní orúkọ Jésù Àmín

BIBELI KIKA: Job 42:7-17

Leave a comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *