THE SEED
“For promotion cometh neither from the east, nor from the west, nor from the south. But God is the judge: He putteth down one and setteth up another.” Psalm 75: 6 – 7
God desires that His children all over the world stand out in any environment they find themselves, spiritually, materially, academically, socially, financially etc. The world is drawn to God through your life when they see a sign of consistent progress in you. God gives promotions but it may not be the way the world gives it. You do not have to lie and cheat in order to move forward in life. There is a kingdom way of advancing, it may come with more character, more discipline, a deeper sense of faith and devotion or a stronger family. God is raising people who will be His ambassador in our time. These people will enjoy divine lifting by revelation. The hand of God will be mighty upon them and their world will celebrate them. Start aiming for the top. Your faith in God will take you there. You have all it takes to be the best in life. Remember, God is in charge of your promotion.
BIBLE READING: Psalm 121 : 1 – 2
PRAYER: Thank you Lord for your promotion in my life; for knowing you and accepting you as my Lord and Saviour, giving me the hope of a better future.
IGBEGA LATI ỌDỌ ỌLỌ́RUN
IRUGBIN NAA
“Nitoripe igbega kì iṣe lati ila-õrun, tabi lati iwọ-õrun, tabi lati gusu. Ṣugbọn Ọlọrun ni onidajọ. Ó gbé ọ̀kan kalẹ̀, ó sì gbé òmíràn ga,” Orin Dafidi 75:6-7
Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ jákèjádò ayé dúró ní àyíká èyíkéyìí tí wọ́n bá rí ara wọn, nípa tẹ̀mí, nípa ti ara, ní ẹ̀kọ́ ìwé, láwùjọ, ní ti ìṣúnná owó àti bẹẹ bẹẹ lọ. Awọn eniyan a máà fa si ọdọ Ọlọrun nipasẹ igbesi aye rẹ, nigbati wọn ba ri ami ilọsiwaju deede ninu rẹ. Ọlọrun n funni ni igbega ṣugbọn ki i ṣe bi araye ṣe n fun ni. O ko ni lati purọ, tabi yan eniyan jẹ lati le tẹsiwaju nínú igbesi aye rẹ. Ọna ijọba ọrùn kan wa fún ilọsiwaju, o le wà pẹlu ìwà diẹ, ìbáwí diẹ, imọ-ijinlẹ ti igbagbọ ati ifọkansin tabi idile ti o lagbara. Ọlọ́run ń gbé àwọn èèyàn dìde tí yóò jẹ́ ikọ̀ rẹ̀ ní àkókò wa. Awọn eniyan yíó gbadun ìgbé dìde atoke wa nipa ifihan. Ọ́wọ Ọlọrun yio si lagbara lara wọn, aiye yio si ṣe ayẹyẹ wọn. Bẹrẹ sí ni ní afoju sọ́na fún igbega. Ìgbàgbọ rẹ ninu Ọlọrun yio mu ọ dé bẹ. O ni ohun gbogbo ti o nilo lati jẹ ẹniti o dara julọ ni igbesi aye rẹ. Ranti, pé Ọlọrun ni oludari igbega rẹ.
BIBELI KIKA: Orin Dafidi 121:1-2
ADURA: Mọ dupẹ lọwọ Oluwa fún igbega mi láyé; fún wípé mo mọ Ọ ati gbigba Ọ ni Olúwa àti Olùgbàlà mi, nipa fí fún mí ni ireti ìgbé ayé tí o dára fún ọjọ iwájú.