KNOWLEDGE: THE POWER TO REIGN
THE SEED
“Therefore my people are gone into captivity because they have no knowledge, and their honourable men are famished, and their multitude dried up with thirst.” — Isaiah 5:13 (KJV)
Lack of knowledge keeps many believers living as victims rather than victors. God has given us the authority to reign in Christ, but without understanding who we are, we live below our inheritance. You are not ordinary. In Christ, you are blessed, favoured, victorious, and seated in heavenly places. Knowledge opens your eyes to see what is already yours in Christ, and empowers you to resist poverty, fear, sickness, and every form of oppression. Beloved, you must align your identity with what God says about you, not what the world says. The more you know, the more you can walk in your authority as a king and a light in your generation.
Reflection: You can only manifest what you truly know.
BIBLE READING: Ephesians 1:17–23
PRAYER: Lord, open my understanding to fully grasp who I am in You, and help me walk in my inheritance daily. Amen.
IMO: AGBÁRA LÁTI ṢÀKÓSO
IRUGBIN NAA
Nítorí náà ni àwọn ènìyàn mi ṣe lọ sí ìgbèkùn nítorí wọn kò ní ìmọ̀, àwọn ọlọ́lá wọn sì ń pa ebi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn sì gbẹ pẹ̀lú òùngbẹ.” – Isaiah 5:13 (KJV)
Àìní ìmọ̀ ń mú kí ọ̀pọ̀ àwọn onígbàgbọ́ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi iya jẹ́ dípò eni ti o borí. Ọlọ́run ti fún wa ní àṣẹ láti jọba nínú Kristi, ṣùgbọ́n láìlóye ẹni tí a jẹ́, a kò lè mo rírì ohun ìní wa. Ìwọ kìí ṣe lásán. Nínú Kristi, a jẹ́ alábùkún, olóore-ọ̀fẹ́, olùṣẹ́gun, tí o jókòó ní àwọn ọ̀run. Ìmọ̀ a maa ṣí ojú re láti rí ohun tí ó ti jẹ́ tìrẹ nínú Kristi, ó sì fún ọ ní agbára láti kojú òṣì, ìbẹ̀rù, àìsàn, àti gbogbo irú ìnilára.
Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ gbọ́dọ̀ so ìdámọ̀ yín pọ̀ mọ́ ohun tí Ọlọ́run sọ nípa yín, kì í ṣe ohun tí ayé ń sọ. Bí ẹ ṣe mọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ ṣe lè rìn ní àṣẹ yín gẹ́gẹ́ bí ọba àti ìmọ́lẹ̀ ní ìran yín.
Asaro: Ohun tí ẹ mọ̀ ní tòótọ́ nìkan ni ẹ lè fi hàn.
BIBELI KIKA: Éfésù 1:17-23
ADURA: Olúwa, ṣí òye mi sílẹ̀ láti mọ ẹni tí mo jẹ́ nínú Rẹ ní kíkún, kí o sì ràn mí lọ́wọ́ láti rìn nínú ogún mi lójoojúmọ́. Àmín.