Quietness And Confidence

THE SEED
For thus saith the Lord GOD, the Holy One of Israel; In returning and rest shall ye be saved; in quietness and in confidence shall be your strength: and ye would not. Isaiah 30:15

Everyone seems to be looking for answers, guidance, and something to lift their spirits, but they don’t look to the Lord for these things. However, God has already addressed them through Isaiah, and if they do not go to him for guidance, their efforts will only result in misery and confusion. The salvation of people has been made simple by Jesus Christ, who now offers salvation to both Israelites and other nations, or Gentiles. All who call on the name of the Lord will be saved because Jesus Christ offered His blood as an atonement for the sin of the world (Acts 2:21). Once you’ve been saved, be calm and rely on the Lord Jesus Christ in any circumstance; when we put our faith in Him, more grace becomes accessible to us, enabling us to triumph over every challenging circumstance. Your heart will be drawn towards Jesus in worship, while your body is at ease and comfy and your eyes are fixed entirely on Him. You will probably feel more inclined to obey Him as a result of this experience. People who make time to spend alone with the Lord discover a fresh source of inner fortitude and quiet assurance.

PRAYER
O Lord, let me not lose that comfort  and inner peace, since accepting you as my Lord and Saviour,  me know you more. Amen.
BIBLE READINGS:  Isaiah 30

     IDAKEJE ATI IGBOYA

IRUGBIN NAA
Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Ẹni-Mimọ Israeli: Ninu pipada oun sisimi li a o fi gbà nyin là; ninu didakẹji ati gbigbekele li agbara yin wa sugbon ẹnyin kò fẹ. Isaiah 30:15

O dabi ẹni pe gbogbo eniyan n wa awọn idahun, itọsọna, ati nkan lati ru ẹmi wọn soke, ṣugbọn wọn ko wo oju Oluwa fun awọn nkan wọnyi. Bí ó ti wù kí ó rí, Ọlọrun ti bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Isaiah, bí wọn kò bá sì tọ̀ ọ́ lọ fún ìtọ́sọ́nà, laálaa wọn yóò yọrí sí ìdààmú àti ìdàrúdàpọ̀. A mu igbala okan awon eniyan wa nipa Jesu Kristi , eni ti o fun Israeli ati awon orile ede miran ni igbala. Gbogbo awọn ti o kepe orukọ Oluwa ni a o gbala nitori Jesu Kristi fi ẹjẹ se ètùtù fun ẹ̀ṣẹ̀ arayé (Iṣe Awọn Aposteli 2:21). Ni kete ti o ba ti ni igbala, farabalẹ ki o gbẹkẹle Oluwa Jesu Kristi ni ipokipo ti o ba wa; nígbà tí awa bási ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀, a o je oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ síi di, tí o mu wa bori awon ipenija. Ọkàn rẹ yoo fa si odo Jesu ninu ifokansin, nigba ti ara yo tu o ti o si ma teju mo oun nikan. Nitori iriri yi, o rorun lati maa se igboran si Oluwa, Awon ti won duro niwaju Oluwa yio ri orisun agbara ati idaniloju pipe.

ADURA
Oluwa, ma je ki n padanu itunu ati ifokanbale, lehin igba ti mo ti gba o gege bi Oluwa ati Olugbala mi, je kin mo o siwaju sii.
BIBELI KIKA: Aísáyà 30

Leave a comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *