REJECT THE SONG OF FOOLS
THE SEED
“It is better to heed the rebuke of a wise person than to listen to the song of fools.” — Ecclesiastes 7:5 (NIV)
Wise correction is a gift from God to keep us from falling into traps. But the enemy counterfeits this with flattery — the “song of fools” that praises wrongdoing and blinds us to the truth. Flattery may feel sweet, but it leads to destruction. For those who belong to Christ, rebuke should be received with an open heart because it sharpens and restores us. Those who encourage your errors are not helping you — they are helping the enemy. Surround yourself with voices that speak truth, even when it stings. It is better to be corrected by a friend than celebrated by a fool.
Reflection: A wise rebuke can save where flattery can destroy.
BIBLE READING: Proverbs 27:3–6
PRAYER: Lord, give me a humble spirit to receive godly correction and reject flattering lies. Amen.
MA SE GBO ORIN ASIWERE
IRUGBIN NAA
“O san lati gbọ́ ibawi ọlọgbọ́n jù ki enia ki o fetisi orin aṣiwère.” – Oníwàásù 7:5
Ìbáwí ọlọ́gbọ́n jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run fun wa ki a má bá ṣubú sínú ìdẹkùn. Ṣùgbọ́n ọ̀tá ń ṣe aiyederu èyí pẹ̀lú ìpọ́nni – orin asiwere tí ó ń yin ìwà àìtọ́ tí ó sì ń mu ni fọ́jú si òtítọ́. Ìpọ́nni lè dùn, ṣùgbọ́n ó ń yọrí sí ìparun. Fún àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi, ìbáwí gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun ti a tewo gbà nítorí pé ó ń ta wá jí, o si mú wa padà bọ̀ sípò. Àwọn tí ó ń pón àṣìṣe rẹ kò ràn ọ́ lọ́wọ́ – wọ́n ń ran ọ̀tá lọ́wọ́ ni. Yí ara rẹ ká pẹ̀lú àwọn ohùn tí ń sọ òtítọ́, kódà nígbà tí ó bá ń dúnni. Ó sàn kí ọ̀rẹ́ kan tọ́ ọ sọ́nà ju kí òmùgọ̀ ṣe ayẹyẹ rẹ̀ lọ.
Asaro: Ìbáwí ọlọ́gbọ́n lè gbà ní là níbi tí ìpọ́nni lè parun.
BIBELI KIKA Òwe 27:3-6
ADURA: Olúwa, fún mi ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ láti gba ìbáwí Ọlọ́run kí n sì kọ irọ́ ìpọ́nni sílẹ̀. Àmín.