YOUR SPIRITUAL INHERITANCE

YOUR SPIRITUAL INHERITANCE

THE SEED

“But to the tribe of Levi he gave no inheritance; the Lord, the God of Israel, is their inheritance, as he promised them.”  Joshua 13:33 (NIV)

When the land of Canaan was divided among the tribes of Israel, the Levites received no physical land. Instead, God Himself became their inheritance. This was a special privilege  a life of depending on divine provision and living close to His presence. As believers, we also have a spiritual inheritance in Christ. Our security, identity, and provision are found not in earthly possessions but in our relationship with God. He promises to supply our needs according to His riches in glory. Don’t measure your worth by material possessions. Your greatest inheritance is God Himself  His presence, His Word, and His promises. These treasures endure beyond time.

Reflection: Your greatest inheritance is not land or gold, but God Himself.

BIBLE READING: Ephesians 1:11–14

PRAYER: Father, thank You for being my inheritance. Help me to trust Your provision always. Amen.

 

OGÚN TÍ Ẹ̀MÍ

IRUGBIN NAA:

“Ṣùgbọ́n ẹ̀yà Léfì ni Mósè kò fi ilẹ̀ ìní fún; OLUWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ìní wọn, gẹ́gẹ́ bí Ó ti wí fún wọn.”  Jóṣúà 13:33

Nígbà tí wọ́n pín ilẹ̀ Kénáánì láàrín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, àwọn ọmọ Léfì kò gba ilẹ̀ ìní bí àwọn ẹ̀yà mìíràn. Dípò bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run tikararẹ̀ di ogún wọn. Èyí jẹ́ ànfàní àkànṣe — ìgbésí ayé gbígbẹ́kẹ̀lé ìpèsè àtọ̀runwá àti gbígbé nítòsí ìwàláàyè Rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́, àwa náà ní ogún tẹ̀mí nínú Kristi. Ààbò, ìdánimọ̀, àti ìpèsè wa kò dá lórí ohun ìní ayé nìkan, bí kò ṣe lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó ṣèlérí láti pèsè gbogbo àìní wa gẹ́gẹ́ bí ògo Rẹ̀. Má ṣe fi ohun-ìní ti ara ṣe ìwọ̀n fún ohun tí o ní nínú Ọlọ́run. Ogún tó ga jù lọ ni Ọlọ́run fúnra Rẹ̀, ìwàláàyè Rẹ̀, Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, àti àwọn ìlérí Rẹ̀. Àwọn ìṣúra wọ̀nyí ni ń dúró títí láé.

ÀṢÀRÒ: Ogún rẹ tó ga jù lọ kì í ṣe ilẹ̀ tàbí wúrà, bí kò ṣe Ọlọ́run tikararẹ̀.

 

BIBLE READING: Éfésù 1:11–14

PRAYER: Bàbá, mo dúpẹ́ fún jíjẹ́ ogún mi. Ràn mí lọ́wọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé ìpèsè Rẹ nígbà gbogbo. Amin.

Leave a comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *