THE SEED
“Now the God of hope fill you with all joy and peace in believing, that ye may abound in hope, through the power of the Holy Ghost.” Romans 15:13
People crave joy and peace deeply and won’t be happy until they have them. Once they do, they will also appreciate them intensely until they are truly filled with these emotions. Doubt creeps in and a believer in Christ Jesus starts to lose many things the moment he or she starts to cease believing. First of all, he loses access to God’s power to move things forward because uncertainty robs people of confidence, and God depends on our faith in Him to bless us (Hebrews 11:6). Second, he ceases to believe the truth of God’s Word, and such a person hardly ever studies the Bible. Jesus Christ urged the Apostle Thomas to maintain his faith in order to dispel his mistrust and unbelief (John 20:27). Christians should pray for one another’s faith so that they may have trust in the Holy Scriptures and the various promises of God contained therein until they have experienced them. Although we don’t always experience joy and tranquillity, in general, these emotions represent the benefits of believing—and they are benefits not just occasionally but always.
PRAYER
Give me the joy of salvation and of heaven.
BIBLE READINGS: Psalms 55
AWỌN ERÉ FÚN GBI-GBAGBỌ
IRUGBIN NAA
Nje ki Ọlọrun ireti ki o fí gbogbo ayọ on alàáfíà kún nyìn ní gbigbagbọ, kí ẹyin kí o le pọ ni ireti nipa agbara Ẹmi Mímọ. Rómù 15:13
Ọpọ eniyan lo ńpongbẹ fún ayọ àti àlàáfíà ti o jinlẹ̀, tí inú wọn kò sí ní dún, àfi ti wọn ba rí gbà. Lọgan ti wọn ba sì ri i gba, wọ́n máa nmọ riri, titi wọn o fí kún fún ayọ yí. Nigbati iyè meji bá wọlé Onigbagbọ ninu Kristi Jésù yíó bẹrẹ sí npadanu ọpọlọpọ nkan , tàbí tí o ba dẹkùn lati máà gbagbọ. La kọ̀kọ, irú onigbagbọ bẹẹ yíó padànu agbara Ọlọrun lati máà tẹsiwaju nitoripe iyemeji máà n mu eniyan padanu ìdánilójú nínú Ọlọrun. Ọlọrun sí máà ngbẹkẹle ìgbàgbọ wá nínú Rẹ lati bukún fún wá (Heberu 11:6). Ìkejì, onigbagbọ yi yio dẹkun ati gbagbọ ninu otitọ ọrọ Ọlọrun, agbára káká ni irú ènìyàn bayi fi máà nka Bíbélì. Jesu Kristi gba Tomasi Àpọsítélì ní iyànjú lati mu ìdúró rẹ nínú ìgbàgbọ, ki o ba le kuro ninu aigbagbọ. (Johannu 20:27). Kristeni gbọdọ máa fi adura ràn ìgbà gbọ ara wọn lọwọ kí wọn bá le ni igbagbọ ninu lilo ọrọ inú ìwé mímọ àti orísirísi àwọn ileri Ọlọrun. Kí í ṣe gbogbo igba ni a máa nní ìrírí ayọ àti ìtura, awọn ìmọ lara yi fara jọ anfani ti o wá nínú ìgbàgbọ; awọn anfani wọnyi kìí ṣe ẹẹkọkan bikòṣe nigbagbogbo.
ADURA
Fún mi ni ayọ igbala ti ọrùn.
BIBELI KIKA: Psalmu 55