A DIVINE ENCOUNTER IN THE FIRE
THE SEED
“And when the Lord saw that he turned aside to see, God called unto him out of the midst of the bush, and said, Moses, Moses. And he said, Here am I.” — Exodus 3:4 (KJV)
When Moses saw the burning bush, it wasn’t just a strange sight; it was an invitation to divine encounter. God used something unusual to capture his attention and draw him closer. In life, there are “burning bush” moments—situations that look threatening, confusing, or overwhelming but are actually God’s way of speaking to us. Instead of focusing on the heat of the situation, we must learn to listen for God’s voice. When He is involved, the fire may burn but it will not consume. Trials become testimonieswhen we allow God to reveal His purpose in them. Every challenging season can lead to a fresh encounter with God. Draw closer, listen carefully, and watch Him turn your pain into wonders.
Reflection: The burning bush may be the doorway to a divine encounter.
BIBLE READING: Exodus 3:1–5
PRAYER: Father, give me the strength to face every situation with courage, and help me hear Your voice through it. Amen.
ÌBÀPADÉ ÀTỌKEWÁ NÍNÚ INÁ
IRUGBIN NAA:
“Nígbà tí Olúwa rí i pé ó yípadà sí apá kan láti wò ó, Ọlọ́run pè é láti inú àárín ìgbẹ́ náà wá, ó sì wí pé, ‘Mósè!’ Òun sì dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’” – Ẹ́kísódù 3:4
Nígbà tí Mósè rí ìgbẹ́ tí ń jó, kì í ṣe ohun àjèjì lásán; ó jẹ́ ìpè sí ìbàpadé àtọ̀runwá. Ọlọ́run lo ara ọ̀tọ̀ láti mú kí Mósè fiyè sí i, kí ó sì fà á sunmọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ní ayé, àwọn àkókò kan wà tí ó dàbí “ìgbẹ́ tí ń jó” — àwọn ipò tí ó dẹ́rùbà ni tàbí danilamú — ṣùgbọ́n ní tòótọ́, wọ́n lè jẹ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run fi ń bá wa sọ̀rọ̀. Dípò kí a máa gbé ọkàn wa sókè lórí bí ìṣòro náà ṣe le tó, a gbọ́dọ̀ kọ́ bí a ṣe ń fetí sí ohùn Ọlọ́run ninu re. Nígbà tí Ó bá wà pẹ̀lú wa nínú ìlàkọjá bẹ́ẹ̀, iná lè máa jó, ṣùgbọ́n kii se fun iparun. Àdánwò maa n pada di ẹ̀rí nígbà tí a bá gba Ọlọ́run láyè láti fi ìfẹ́ Rẹ hàn nínú won. Gbogbo àkókò ìpèníjà lè di ẹnu-ọ̀nà sí ìbàpadé pẹ̀lú Ọlọ́run. Sunmọ́ Ọ, tẹ́tísílẹ̀ dáradára, kí o sì wo bí yóò ṣe yí irora rẹ padà di iyanu.
ÀṢÀRÒ: Igbẹ́ tí ń jó lè jẹ́ ẹnu-ọ̀nà sí ìbàpadé àtọ̀runwá.
BIBELI KIKA: Ẹ́kísódù 3:1–5
ADURA: Baba, fún mi ní agbára láti kojú gbogbo ipò pẹ̀lú ìgboyà, kí o sì ràn mí lọ́wọ́ láti gbọ́ ohùn Rẹ nípasẹ̀ rẹ̀. Amin.