FAITH THAT SILENCES DOUBT
THE SEED
“Let us hold fast the confession of our hope without wavering, for He who promised is faithful.” — Hebrews 10:23 (NKJV)
God’s Word calls us to hold firmly to the confession of our faith. Speaking faith fuels confidence. In moments of delay or uncertainty, our words and posture must remain anchored in what God has promised. Doubt is a subtle thief. It creeps in quietly to weaken our faith and delay our blessings. But God does not need perfection to fulfil His Word—He needs unwavering trust. When we inhale confidence and exhale doubt, we align ourselves with His faithfulness. The One who made the promise is unchanging. Trusting Him will never put you to shame.
Reflection: Confidence in God is the antidote to doubt.
BIBLE READING: Psalm 46:1–5
PRAYER: Father, I exhale every spirit of self-doubt and inhale divine confidence to walk in Your promises. Amen.
ÌGBÀGBỌ́ TÍ Ó MU IYÈMÉJÌ DÁKẸ́
IRUGBIN NAA:
“ Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mu ṣinṣin ni àìṣiyèméjì; (nítorí pé olóòtítọ́ ní ẹni tí o ṣe ìlérí). — Hébérù 10:23
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pe wa láti di ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ wa mú ṣinṣin. Oro igbagbo maa n fun igboya ni agbara. Ní àwọn àkókò ìdádúró tàbí àìdánilójú, ọ̀rọ̀ wa àti ìdúró wa gbọ́dọ̀ dúró lórí ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Iyèméjì jẹ́ olè arekereke. Ó ń wọlé ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ láti sọ ìgbàgbọ́ wa di aláìlágbára. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò nílò pipe wa; Ó nílò ìgbẹ́kẹ̀lé wa. Nigba ti a ba ni ìgboyà ninu Re, ti a sì ti iyèméjì jade, ó jásí wipe a wa ni ìbámu pelu òtítọ́ Re. Ẹni tí ó ṣe ìlérí kò yí padà. Igbekele ninu Re ki yoo doju ti o.
ÀṢÀRÒ: Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run ni a le fi koju iyèméjì.
BIBELI KIKA: Sáàmù 46:1–5
ADURA: Baba, mo tu gbogbo ẹ̀mí iyèméjì sílẹ̀, mo sì gba ìfọkànbalẹ̀ àtọ̀runwá. Amin.